Faith Adebọla
Yooba bọ, wọn ni a ki i sọ pe k’ọmọde ma ṣe dẹtẹ, bo ba ti le da inu igbo gbe. Eyi lọ wọ bi Adajọ Bọla Ọṣunsanmi ti ile-ẹjọ Majisireeti kan to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, ṣe paṣẹ pe ki wọn ṣi lọọ fi ọmọdekunrin ẹni ọdun mẹtala kan ti wọn forukọ bo laṣiiri sahaamọ ti wọn maa n tọju awọn ọmọde to ba daran si, titi ti igbẹjọ yoo fi tẹsiwaju lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o tan ọmọ alaabagbele wọn kan tọjọ ori ẹ kou ju ọdun mẹfa pere lọ, o si fipa ba a laṣepọ.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, lawọn agbofinro wọ ọmọdekunrin afurasi naa lọ sile-ẹjọ Ikẹja ọhun.
Alaye ti Agbefọba, ASP Raji Akeem, ṣe nipa iṣẹlẹ yii ni pe inu oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni afurasi yii huwa palapala ọhun.
O ni ọdọ baba ati iya rẹ lọmọ ọhun n gbe, nigba ti ọmọọdun mẹfa to ki i mọlẹ jẹ ọmọ alajọgbele wọn, toun naa n gbe lọdọ awọn obi tiẹ.
Wọn ni lọjọ kan ti ile da, tawọn obi mejeeji ko si nile, lọmọkunrin elerokero yii dọgbọn tan ọmọdebinrin yii wọ yara wọn, o bọ pata nidii ẹ, o si fipa ba a sun.
Raji ni iwa ti afurasi yii hu ta ko isọri igba o le mẹwaa, iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko ti wọn ṣatunṣe si lọdun 2015.
Lẹyin alaye yii, Onidaajọ Ọsunsanmi ni ki wọn ko gbogbo faili ẹsun naa sọwọ si ẹka to maa n gba awọn adajọ nimọran l’Ekoo fun itọsọna wọn.
Lẹyin naa lo ni ki wọn ṣi lọọ fi afurasi pamọ sahaamọ awọn majeṣin ọdaran, titi di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.