O ṣẹlẹ, ọkọ Lizzy Anjọrin n rin ni bebe ẹwọn, eyi lohun to ṣe

Monisọla Saka

Pẹlu bi ọrọ to wa nilẹ yii ṣe n lọ, afaimọ ni ki ọkọ gbajugbaja oṣerebinrin onitiata ilẹ wa nni, Lizzy Anjọrin, iyẹn Alaaji Lateef Lawal, ma ṣẹwọn.

Ọkunrin gbajumọ nidii ilẹ tita yii ni wọn ti fẹsun kan pe o fagidi gba ilẹ ti Arabinrin Faith Ojo, oniṣowo ọmọ ilẹ Naijiria kan to fẹẹ fi kọle awọn ọmọ alainiyaa.

Gẹgẹ bi ẹjọ ọrọ yii ṣe ti wa niwaju ile-ẹjọ Majisireeti Oyingbo, Ebute-Mẹta, nipinlẹ Eko, awọn olujẹjọ ti wọn fẹsun kan ni Alaaji Sulaimon Okun-Ajah, Eti-Ọsa, nipinlẹ Eko, Alaaji Lateef Lawal, ti i ṣe ọkọ Lizzy Anjọrin, atawọn mi-in.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn wo ile ti wọn n kọ lọ lori ilẹ Arabinrin Faith Ojo, ti wọn tun pada waa fagidi sọ ọ di tiwọn.

Pẹlu gbogbo akitiyan awọn agbofinro Zone 2 lati yanju iwa odaran naa, ati lati fofin gbe awọn afurasi ti aje iwa ibajẹ ṣi mọ lori ọhun, wọn ni Lawal mori bọ lasiko ti wọn waa fi panpẹ ọba gbe gbogbo wọn lọjọ karun-un, oṣu Keji, ọdun yii, lagbegbe Ikoyi, nipinlẹ Eko. Awọn yooku rẹ tọwọ tẹ yii ni wọn ti n gbatẹgun lọgba ẹwọn ba a\ ṣe n sọ yii.

Lara awọn olujẹjọ ọhun ni Rasheed Olukosi, Muniru Olukosi, Saheed Olukosi, Kareem Wasiu Jagun, Sulaimon Bọlaji, Muritala Musbau, Kẹhinde Jagun ati Lateef Lawal funra ẹ.

Miliọnu lọna ọgbọn Naira (30m), ni obinrin yii beere fun gẹgẹ bii owo gba-ma-binu, ki owo eto ẹjọ ati iwe ẹsun si ọdọ ọlọpaa si tun wa lọrun wọn.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i rọna yanju ọrọ beeli fawọn to wa latimọle, ahesọ ọrọ to n lọ kaakiri ni pe Lizzy Anjọrin ti n lo ipo rẹ gẹgẹ bii gbajumọ lawujọ lati gba awọn afurasi to wa lẹwọn jade.

Ṣe awuyewuye ti n lọ tẹlẹ pe wọn n wa Ọgbẹni Lawal, lati tubọ fidi ẹ mulẹ pe loootọ lọrọ naa, Faith Ojo kọ ọ si oju ikanni Instagram rẹ bayii pe, “Ẹ ku deede asiko yii o, ẹyin eeyan. Ọrọ iroyin to n ja ran-in nipa ọkọ Lizzy Anjọrin, Alaaji Lateef Lawal, ti wọn fẹsun ilẹ jijagba l’Ekoo kan oun atawọn kan ti de etiigbọ mi.

“Bẹẹ ni, mo le fidi ẹ mulẹ fun yin pe bẹẹ lọrọ ri, ati pe emi gangan ni mo ni ilẹ ọhun. Lọdun mẹrin sẹyin ni mo ra ilẹ ti wọn n sọrọ nipa ẹ yii. Ero mi si ni lati fi kọ ile awọn ọmọ alainiyaa, lati fi pese ibugbe to rọrun fawọn ọmọde to wa labẹ ileeṣẹ ẹlẹyinju aanu mi.

“Mi o ni i le sọrọ pupọ ju bayii lọ na lori ọrọ ọhun, nitori ọrọ naa ti wa niwaju ile-ẹjọ. Mo nigbagbọ to rinlẹ ninu eto idajọ orilẹ-ede Naijiria, o si da mi loju pe ohun to tọ, to si yẹ, ni wọn maa ṣe.

“Ọrọ ẹjọ yii yoo duro bii ẹkọ fawọn eeyan mi-in ti wọn fẹẹ jẹ nibi ti wọn ko ṣe si. Iwa ibi ni ọrọ ka maa gba ilẹ onilẹ, ati awọn iwa ti ko daa mi-in. Ọlọrun yoo bu kun gbogbo yin”.

Eyi ni oṣerebinrin to gbajumọ daadaa nni, Iyabọ Ojo, to jẹ ọsan ati oru loun pẹlu Lizzy Anjọrin, ti ija to gbona girigiri si n lọ laarin wọn lọwọ, agaga lẹyin ti wọn tun fẹsun jibiti kan Lizzy ninu ọja Idumọta l’Ekoo, ri to fi gbe e sori ikanni rẹ lori ayelujara pe: “Gbogbo awọn iya oṣi rẹ da, awọn oponu ti wọn n ja, awọn ayederu onijagbara atawọn oniroyin ori ayelujara ti wọn lemi ni mo wa nidii bi wọn ṣe dunran ole mọ ọ da? Mo lero pe ẹ o tun ni i sọ pe emi ni mo tun ṣe eleyii naa. Radarada, awọn alaigbadun. Isinku yin o ni jere”.

Bayii ni Iyabọ Ojo kọ si abẹ ọrọ ti arabinrin to ni ilẹ naa kọ.

Tẹ o ba gbagbe, nibẹrẹ oṣu Keji yii, ni wọn fẹsun jibiti kan Lizzy Anjọrin, ti wọn lo fi alaati feeki sanwo ọja l’Ekoo. Ṣugbọn Lizzy ti ni ọrọ ko ri bẹẹ, o ni irọ to jinna si ootọ ati iṣẹ ọwọ awọn ọta ni gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun yii.

Nitori ẹ naa si ni Iyabọ Ojo ṣe la a mọlẹ pe, tawọn kan ba wa nidii bi wọn ṣe fẹsun ole kan iyawo, ṣe awọn yẹn naa ni wọn tun wa nidii ole ilẹ jijagba ti kootu fi kan ọkọ.

 

Leave a Reply