Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gbajugbaja agbẹjọro kan to filu Akurẹ ṣebugbe, Amofin Fẹmi Emmanuel Emodamori, ti fun ajọ eleto idibo lorilẹ-ede yii lọjọ meje pere lati fi awọn iwe-ẹri ti igbakeji Gomina, Ọnarebu Agboọla Ajayi, fẹẹ fi dije ninu eto idibo to n bọ lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun ta a wa yii sita.
Ninu lẹta gigun kan ti ọga awọn agbẹjọro yii kọ si ajọ naa lo ti fi ye wọn pe, ohun to lodi sofin patapata ni bi wọn ko ṣe lẹ iwe-ẹri awọn oludije mọ orukọ ti wọn fi sita lọjọ kọkanlelogun, osu kẹjọ, ọdun ta a wa yii.
Emodamori ni ibeere oun wa ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin Naijiria, o ni gbogbo igbesẹ to yẹ labẹ ofin loun ti gbe lori awọn ohun ti oun n beere lọwọ ajọ eleto idibo.
Amofin yii ni oun ni idaniloju pe ayederu iwe-ẹri ni Ajayi to jẹ oludije ẹgbẹ ZLP fun ajọ eleto idibo.
O ni iyalẹnu lo jẹ pẹlu bo ṣe jẹ iwe-ẹri oniwee mẹwaa nikan lọkunrin naa fi silẹ pẹlu ariwo to n pa fawọn eeyan pe oun kẹkọọ-jade lẹka imọ ofin ni Fasiti Igbinedion.
O ni oṣu kẹrin si ikarun-un ọdun 2004 ni Ajayi sọ pe oun kẹkọọ jade nileewe girama kan to wa ni Mobọlọrunduro, ṣugbọn to jẹ pe laarin asiko yii, (ọdun 2003 si 2004) lo fi jẹ alaga afunsọ nijọba ibilẹ Ẹṣẹ-Odo.
Aarin ọdun 2004 si 2007 lo ni wọn tun dibo yan an gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ naa, leyii ti ko fi ṣee ṣe fun un ko wa nile-iwe girama gẹgẹ bii akẹkọọ lasiko kan naa.
O ni irọ mi-in ti Ajayi tun pa ni ọdun kan to ni oun tun lọọ lo nileewe awọn aṣofin, to si ni wọn fun oun ni iwe-ẹri ‘mo yege’ lọdun 2010, ṣugbọn to jẹ pe aarin ọdun 2007 si 2011 lo fi wa nile-igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, nibi ti wọn dibo yan an si lati ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Ilajẹ ati Ẹsẹ-Odo.
Emadamori ni niwọn igba ti orukọ Ajayi ti wa ninu awọn oludije ti ajọ eleto idibo fi sita lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2020, o ni ẹnikẹni lo lẹtọọ labẹ ofin lati beere fun awọn iwe-ẹri to fẹẹ fi dije sipo gomina to n poungbẹ fun.
Agbẹjọro yii ni oun ṣetan ati wọ ajọ eleto idibo lọ sile-ẹjọ lẹyin ọjọ meje naa ti wọn ba fi kuna ati gbe igbesẹ lori ohun ti oun n beere fun.
Ọsẹ bii meji sẹyin lawuyewuye ti n suyọ lori ọrọ iwe-ẹri oniwee mẹwaa ti igbakeji gomina ọhun fi silẹ lọdọ ajọ eleto idibo dipo ti iba fi fun wọn ni iwe-ẹri awọn amofin to sọ pe oun ni. Oludamọran agba rẹ lori ọrọ iroyin, Allen Ṣoworẹ, da awọn alatako yii lohun nigba naa pe ọga oun ko nilo ati fi iwe-ẹri fasiti rẹ silẹ niwọn igba to jẹ pe ti oniwee mẹwaa pere ni wọn n beere fun nibi to ti fẹẹ dije.