Ijọba ti tun fi kun owo epo bẹntiroolu o!

Oluyinka Soyemi

Lẹyin ti ijọba apapọ kede afikun owo epo si naira mọkanlelaaadọjọ (151.56) fun awọn onileepo, ẹgbẹ awọn to n ta epo bẹntiroolu ti kede pe naira mejilelọgọjọ (N162) lawọn yoo maa ta a.

Lonii ni ọga ileeṣẹ Petroleum Products Marketing Company (IPMAN) to jẹ ọkan lara awọn ẹka ileeṣẹ epo ilẹ yii (NNPC), D. O Abalaka, kede pe afikun gun owo tawọn onileepo yoo maa gbe epo lọdọ awọn.

Eyi lo jẹ ki alaga IPMAN, ẹka tilẹ Yoruba, Alhaji ‘Dele Tajudeen, kede pe naira mejilelọgọjọ lawọn yoo maa ta a bayii.

O ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti woye iye ti wọn yoo san lori gẹnẹretọ ti wọn yoo maa lo nileepo, iyẹ ti wọn yoo maa gbe epo lati idubo ti wọn ti n ta a atawọn owo ti wọn yoo san fawọn alaṣẹ, eyi lo si fa iye tawọn fẹẹ maa ta a lati asiko yii.

Leave a Reply