Faith Adebọla, Eko
Iya Whitney Adeniran, ọmọọdun mejila to n kawe nileewe Chrisland Group of Schools, ko too doloogbe lojiji lọsẹ mẹta sẹyin lasiko ti wọn n ṣe ere idaraya onile-jile wọn, Abilekọ Blessing Adeniran, ti sọ pe ki i ṣe aarẹ ara lo pa ọmọ oun, bẹẹ ni iku rẹ ki i ṣe ti majele, o ni ayẹwo ti fidi ẹ mulẹ pe niṣe lọmọbinrin naa gan mọna, o ni ina ẹlẹntiriiki ni wọn lo gbe e, amọ awọn alaṣẹ ileewe naa fẹẹ daṣọ bo ootọ lori.
Ninu fọran fidio kan ti obinrin to n ṣọfọ lọwọ naa ṣe lori ẹrọ ayelujara laṣaalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu Kẹta yii, tẹkun-tomije ni mama naa fi ṣalaye bọrọ ṣe jẹ gan-an, o ni:
“Mo dupẹ lọwọ gbogbo yin fun atilẹyin ati aduroti yin o, bẹẹ ṣe n pe wa lori aago, tẹ ẹ si tun n fi atẹjiṣẹ ṣọwọ si wa pe ka le mọkan le, ka le ṣara giri lasiko ọfọ nla yii, ẹ ṣee o.
“Esi ayẹwo ijinlẹ ti wọn ṣe lori oku ọmọ wa ti jade o, ina ẹlẹntiriiki lo pa Desọla. Ọmọ mi gan mọna ni!
“Ha, oju mi ti ri to lati ọsẹ meji sẹyin, ọla (iyẹn Tọsidee yii), lo maa pe ọsẹ kẹta tọmọ mi fo ṣanlẹ, to ku. Awọn alaṣẹ ileewe ẹ si fẹẹ da mi lori ru, pẹlu irọ banta-banta ti wọn n gbe jade ninu lẹta ati atẹjade wọn pe ara ọmọ mi ni ko ya, aarẹ kan ti wa lara ẹ tẹlẹ ni, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
“Awọn eeyan sọrọ buruku si emi ati famili mi. Bẹẹ ọmọ yẹn gan mọna nileewe wọn ni. Mo sọ fun wọn nileewe yẹn pe mi o fẹ wahala o, niṣe ni ki wọn dahun awọn ibeere ti mo n bi wọn, kaka ki wọn dahun, wọn wa sile wa, wọn n kunlẹ fun wa.
“Mo bẹ wọn, mo parọwa fun wọn. Mo ni ‘Misiisi Amao, ẹ dakun, mi o mọ bi wọn ṣe n ṣe ọtọpusi, iyẹn ayẹwo ijinlẹ ti wọn n ṣe lati mọ iru iku to pa ẹnikan, mo ni mo ti ṣewadii lori intanẹẹti, ohun ti mo si ka nipa ẹ ṣẹru baayan. Mo bẹ wọn pe ọmọ mi ti ku, ẹ ma tun jẹ ki wọn bẹrẹ ayẹwo ijinlẹ kan lori ẹ, tori niṣe ni wọn maa kun oku yẹn si wẹwẹ. Mo bẹ yin lorukọ Ọlọrun, abiyamọ ṣaa lẹyin naa, ẹ ba mi wadii iku to pa ọmọ mi lojiji kẹ ẹ si sootọ nipa ẹ.’
Esi ti wọn fun mi ni pe awọn naa ko mọ. Wọn kọ lati ṣewaadi, wọn o fẹẹ sootọ.
Wọn ti kun ọmọ mi si wẹwẹ lati ṣayẹwo bayii o, wọn ti la a bi wọn ṣe fẹẹ la a. Wọn mu ẹdọ ẹ, kindinrin ẹ, ifun, ẹjẹ, ọpọlọ, egungun atawọn ẹya-ara kan ninu agbẹdu ẹ fun ayẹwo ijinlẹ. Ẹ wo bi wọn ṣe jẹ ki wọn sọ oku ọmọ mi da nitori ileewe Chrisland ko fẹ ki wọn tabuku orukọ tiwọn.” Bẹẹ niyaa ọmọbinrin naa sọ bo ṣe n daro iku ọmọ wọn.
Tẹ ẹ o ba gbagbe, ki wọn too gbe oku ọmọ naa lọ fun ayẹwo ni baba oloogbe naa, Dokita Micheal Adeniran, ti sọ pe ohun toun foju ara oun ri nigba toun lọọ wo oku ọmọ oun, o loun mọ pe ina ẹlẹntiriiki lo pa a, tori bi oku ọmọ naa ṣe dudu họhọ lẹsẹkẹsẹ to ku tan.
Amọ ninu atẹjade tawọn alaṣẹ ileewe Chrisland fi lede lori iku Whitney, wọn niṣe lo kan ṣadeede ṣubu lulẹ laarin awọn ẹlẹgbẹ rẹ, awọn si ṣugbaa ẹ, amọ ọmọ naa papa ku.
Latari iku akẹkọọ yii, ijọba ipinlẹ Eko ti ti ileewe naa pa lẹyẹ-o-sọka, ti wọn si lawọn maa ṣewadii nipa iṣẹlẹ ibanujẹ naa.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni wọn lọọ sinku ọmọdebinrin yii. Gbogbo awọn mọlẹbi, ọrẹ ati ojulumọ lo bara jẹ lasiko isinku naa. Ko ti i sẹni to mọ igbesẹ ti awọn obi ọmọ yii yoo gbe pẹlu aṣiri iku ọmọ naa ti o ti tu sita bayii.