Ayẹyẹ ọjọọbi Anọbi: Ijọba kede Ọjọbọ, Tọsidee, gẹgẹ bii isinmi lẹnu iṣẹ

Ijọba apapọ ti ya Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, sọtọ gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lati ṣami ọjọọbi Anọbi Muhammed (SAW)

Rauf Arẹgbẹṣọla to jẹ minisita fun ileeṣẹ to n ri si eto abẹle, iyẹn Ministry of Interior, lo sọ eyi di mimọ.

O waa ki gbogbo Musulumi jake-jado orileede yii atawọn ti wọn wa loke okun ku oriire pe ajọdun Mọludi Nabiyu ti ọdun yii tun ṣoju ẹmi wọn.

Beẹ lo rọ wọn lati ṣe amulo ẹmi ifẹ, suuru ati ipamọra to jẹ abuda Anọbi Muhammed (SWA). O ni nipa ṣiṣe beẹ ni yoo mu alaafia ati aabo wa ni ilẹ wa.

 

Leave a Reply