Boya ni Ayodeji ati Ọrẹ yii koni ṣewọn o, Ọmọ Yunifasiti FUOYE ni wọn pa
Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Afaimọ ni ki ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun (22), kan, Akamọ Ayọdeji ati ọrẹ rẹ, Abdullahi Abu, ma ṣẹwọn pẹlu bi awọn ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ṣe ṣe afihan wọn pe awọn ni wọn pa ọmọ yunifasiti kan, Akọmọlafẹ Tolulọpẹ, to wa ni ọdun ki-in-ni nileewe giga naa.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe Ayodeji ati ọrẹ timọ-timọ rẹ Abu, ṣe akọlu sí Akọmọlafẹ Tolulọpẹ to jẹ akẹkọọ Yunifasiti ijọba apapọ to wa ni Ọyẹ-Ekiti, ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2019, ni awọn ọrẹ meji yii tio wa ni akasọ kinni ni ile iwe.
Ninu akọlu naa ni wọn ti da egbo si gbogbo ara ati ori rẹ. Awọn alaaanu kan lo gbe e lọ sileewosan. Nibi to ti n gba itọju lọwọ lo ti pe darukọ Ayọdeji ati ọrẹ rẹ pe awọn ni wọn kọ lu oun.
Lẹyin ti Tolulope pe orukọ awọn mejeeji yii tan lo jade laye, nitori apa to wa lori ati gbogbo ara rẹ ti pọ ju.
Latigba yii ni awọn ọlọpaa ti n wa Ayodeji ati ọrẹ rẹ yii, nitori niṣe ni wọn lọọ fara pamọ ni kete ti wọn gbọ pe Ọmọ yunifasiti yii pe orukọ wọn.
Abutu sọ pe laipẹ yii ni ẹnikan ta awọn awọn ọlọpaa ẹka ọtẹlẹmuyẹ lolobo pe awọn ọdaran mejeeji yii wa ni Ọrin-Ekiti, ti wọn si gbera lati lọọ mu wọn.
O fi kun un pe awọn ọdaran mejeeji ti jẹwọ pe loootọ ni awọn ṣeku pa oloogbe to jẹ ọmọ ileewe giga fasiti FUOYE.
Abutu ni wọn yoo ko wọn lọ sile-ẹjọ ni kete ti iwadii ba pari