Azeez pariwo ni kootu: Mi o fẹẹ ku bayii, adajọ, ẹ tu emi ati Rọqeebat ka

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Lẹyin ti baale ile kan, Azeez Ibrahim, tu gbogbo aṣiri iwa buruku ọwọ iyawo ẹ, Rọqeeba, niwaju ọkẹ aimọye eeyan ni kootu ibilẹ kan to wa laduugbo Akérébíata, niluu Ilọrin, nitori ki adajọ le fopin si ajọṣepọ to wa laarin awọn mejeeji, adajọ ti tu igbeyawo naa ka.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ni baale ile kan, Azeez Ibrahim, ṣalaye niwaju ile-ẹjọ pe niṣe loun maa n fẹẹ le tọ sara ni gbogbo igba ti oun ba ti foju kan iyawo oun. Idi ni pe ki i fi oun lọkan balẹ rara, niṣe lo maa n gbe oun lọkan gbona ni gbogbo, oun ko si ṣetan lati ku bayii loun ṣe fẹ ki adajọ tu awọn ka.

Ibrahim ni, “Mo fẹ ẹ niṣu-lọka ni, ki i ṣe pe wọn fi wa fun ara wa, mo pade ẹ, mo kọ ẹnu ifẹ si i, o si gba fun mi. O ti bimọ meji fun mi, ṣugbọn ọrọ rẹ ti su mi bayii, ti mo si fẹ ka pin gaari’’.

Azeez to peyawo ẹ lẹjọ yii fi kun un pe obinrin naa ki i mojuto awọn ọmọ, o loun loun maa n lọọ gbe awọn ọmọ nileewe, ọpọ igba loun si maa n pe e yi ko ni i gbe e, nigba mi-in, o le pa foonu rẹ.

O waa rọ ile-ẹjọ lati fopin si igbeyawo to wa laarin oun ati olujẹjọ, bẹẹ lo ni oun ṣetan lati maa gbọ gbogbo bukaata awọn ọmọ.

Ninu ọrọ Roqeeba ti i ṣe olujẹjọ, o sọ fun ile-ẹjọ pe oun gan-an alara ti ṣetan lati kọ ọkọ oun, kawọn yaa tete pin gaari lo maa daa.

Niwọn igba to ti foju han pe ko si ifẹ mọ laarin awọn mejeeji, Adajọ Yunusa Abdullahi tu igbeyawo to wa laarin tọkọ-taya naa ka, o ni ki iyawo wa ni mimọ fun oṣu mẹta nile-ọkọ rẹ ko too fẹẹ ọkunrin miiran.

Lẹyin eyi lo ni ki wọn pada wa lọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, lati gbọ idajọ lori akata ẹni ti awọn ọmọ yoo wa.

 

Leave a Reply