Iru ki waa leleyii, baale ile kan binu yinbọn para ẹ ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ki Ọlọrun mọ jẹ ka ri iku ojiji, ṣe ni ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta kan, Ọlarewaju Abidoye, ku lojiji nigba to yinbọn pa ara ẹ ninu yara rẹ, niluu Koro, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ni iroyin tẹ ALAROYE lọwọ pe lọsan-an ọjọ yii ni ọkunrin ọhun gbe ibọn ibilẹ kan, to si yin in pa ara rẹ ni agboole Ore, niluu Koro, to si gbabẹ lọ sọrun alakeji.

Wọn ni Abidoye, ko kọ iwe kankan silẹ lati sọ idi pataki to fi sẹku pa ra ẹ, ṣugbọn ibọn to fi para ẹ ni wọn ba ninu yara ẹ.

Titi digba ta a n ko iroyin yii jọ, ko sẹni to mọ idi ti ọkunrin naa fi da ẹmi ara ẹ legbodo.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, sọ pe oun ko ti i le sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa bayii, ṣugbọn lẹyin iwadii lẹkun-un-rẹrẹ, oun yoo ba awọn oniroyin sọrọ.

Leave a Reply