Ọlawale Ajao, Ibadan
Oku eeyan lawọn oṣiṣẹ ati ara ileeṣẹ Nigerian Brewries, lọna marosẹ Ibadan si Ile-Ifẹ, ṣadeede ji ri laaarọ kutu ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to pari yii.
Lati ọna jinjin rere la gbọ pe ọkunrin kan ti waa pokunso si adugbo naa, nitori ko si ẹni to da a mọ ninu awọn araadugbo ọhun.
Olugbe adugbo ọhun kan, Ṣeyi Babatunde, to fidi iroyin yii mulẹ fun akọroyin wa sọ pe “Ọkunrin kan pokunso si ara igi kan lorita Brewery, l’Alakia.
“Mo ro pe lati ọna jinjin kan lo ti waa para ẹ sibẹ nitori ko ma baa ri ara ile ẹ tabi ẹnikankan di i lọwọ igbesẹ to fẹẹ gbe.
“Ohun to tiẹ n ba wa lẹru tẹlẹ ni ki oorun oku yẹn ma lọọ maa daayan laamu laduugbo. Ṣugbọn awọn ọlọpaa ti waa palẹ rẹ mọ laipẹ yii.”
Agbenusọ tuntun fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni “awọn ọlọpaa lati teṣan Ẹgbẹda ti gbe oku yẹn lọ si aaye ti wọn n gbe oku pamọ si nileewosan Adeọyọ, n’Ibadan.”
O ni awọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii, lati mọ iru eeyan ti ọkunrin naa jẹ ati idi to ṣe da ẹmi ara rẹ legbodo.