Baba arugbo yii fipa ba ọmọ ọdun mẹrin laṣepọ

Faith Adebọla

Kin ni baba arugbo ẹni ọdun marundinlọgọrin ti wọn porukọ ẹ ni Isa Nana Okpoku yii le jẹ yo debi to fi wo ṣunṣun, ti ko ri ẹlomi-in ju ọmọ aburo iyawo ẹ, ọmọọdun mẹrin pere lọ to ki i mọlẹ, to si fipa ba a laṣepọ? Ibeere yii lọpọ eeyan to gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun n beere, bo ṣe n ṣe wọn ni kayeefi, bẹẹ lawọn eeyan n wọn baba agbaaya oniṣekuṣe naa lepe. Wọn niwa ọbayejẹ ti ko ṣee gbọ seti lafurasi ọdaran yii hu.

Ilu Daddare, nijọba ibilẹ Obi, nipinlẹ Nasarawa, niṣẹlẹ yii ti waye, gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Rahman Nansel, ṣe sọ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu Kejila yii.

O ni ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Abamẹta, Satide to ṣaaju lawọn aladuugbo kan mẹjọ baba naa wa si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ilu Obi, alẹ ọjọ naa lawọn si tẹle wọn lọ sile tafurasi ọdaran naa n gbe, iwadii ranpẹ ti wọn ṣe si fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, eyi lawọn ṣe fi pampẹ ofin gbe e lẹsẹkẹsẹ.

O ni ile kan naa, yara kan naa, ni baba arugbo yii ati ọmọ aburo iyawo rẹ ọhun n gbe, awọn o si ri iyawo lọọdẹ rẹ, eyi to mu ko rọrun fun un lati fẹtan mu ọmọbinrin naa sọdọ, to si ṣe e baṣubaṣu.

O lawọn gbe ọmọdebinrin naa lọ sileewosan lati mọ ipo to wa, ibẹ lawọn dokita ti ṣe ayẹwo iṣegun fun un, ti wọn si fidi ẹ mulẹ pe ẹnikan ti ja ibale ẹ tipatipa, tọhun si si da ọgbẹ si i loju ara.

Wọn beere lọwọ Isa, ohun to sun un dedii iwa abeṣe to hu, amọ ko fesi, gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ṣe wi, wọn ni niṣe lo kawọn gbera bii atọọle, to n wolẹ ṣun-un.

Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa, Maiyaki Mohammed Baba, ti gbọ si iṣẹlẹ yii, o si ti paṣẹ ki awọn ọtẹlẹmuyẹ tubọ ṣewadii ijinlẹ si i lori ẹ, o ni ki afurasi naa ṣi wa lakata wọn na.

Lẹyin iwadii lo ni awọn maa wọ ọ lọ sile-ẹjọ, nibi ti yoo ti kawọ pọnyin sọ tẹnu ẹ.

Leave a Reply