Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn iṣẹlẹ gbankọgbi to n waye lojoojumọ nijọba ibilẹ Akinyẹle, nigboro Ibadan, la n wi lati ọjọ yii ti a ko ti i sọ ọ tan, n ni baba ẹni ọdun mejilelogoji (42) kan, Effiom Etowa, to jẹ olugbe Akinyẹle yii kan naa ba tun ki ọmọ bibi inu ẹ mọlẹ, o si fipa ba a laṣepọ titi ti idi ọmọ naa fi faya.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹfa, ọdun 2020 yii, ni baba to n gbe adugbo Tinuoye Estate, laduugbo Ọjọọ, n’Ibadan yii, wo ọmọ ẹ ṣunṣun, to si ko ibasun fun un lasiko ti ko si iyawo ẹ ti i ṣe iya ọmọ naa nile.
Ohun to tubọ mu ki ọrọ naa buru jai ni pe ọmọ ọhun ko ti i dagba rara, ọmọọdun mẹta pere ni.
ALAROYE gbọ pe nigba ti iya ọmọ de, ori ẹkun lo ba a, to si ṣakiyesi pe ẹjẹ n jade loju ara ẹ, ati pe ko le rin daadaa mọ.
Esi to gbọ lẹnu ọmọ yii ya a lẹnu nigba to bi i leere ohun to ṣe e. Ọrọ yii di ariwo tọkọ-tiyawo, debi ti awọn ara adugbo pe le wọn lori, ko too di pe wọn fi iṣẹlẹ naa to ajọ ẹṣọ alaabo ilu ta a mọ si sifu difẹnsi leti lọfiisi wọn to wa l’Ọjọọ, n’Ibadan.
Oṣiṣẹ ajọ NSCD, iyẹn awọn sifu difẹnsi ni wọn gbe Etowa lọ si kootu Majisireeti to wa laduugbo Iwo Road, n’Ibadan, fun ẹsun ibalopọ lọna aitọ lọjọ Ẹti, Furaide, to kọja.
Ẹjọ naa run Onidaajọ Taiwo Ọladiran ninu to bẹẹ ti ko fi faaye silẹ fun Etowa lati wi awijare kankan, niṣe lo paṣẹ pe ki wọn fi olujẹjọ naa sinu ahamọ awọn sifu difẹnsi titi dọjọ ti igbẹjọ naa yoo tun waye.
Nigba to n sun igbẹjọ ọhun siwaju di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje, ọdun yii, Onidaajọ Ọladiran sọ pe inu ahamọ ọgba ẹwọn loun iba sọ olujẹjọ naa si bi ko ṣe nitori ajakalẹ arun Korona to gbaye kan, ko ma di pe wọn yoo tibẹ ko arun buruku naa ran an, tabi ki oun paapaa ko o ran awọn ero ọgba ẹwọn, iyẹn bi ẹni to larun naa lara ba wa nibẹ.