Ẹja panla miliọnu mẹta aabọ naira ti Ode atọrẹ ẹ ji sọ wọn dero kootu

Faith Adebọla, Eko

Arokan ni wọn lo n mu ẹkun asun-un-da wa, arokan ọhun lo ṣẹlẹ si Ọgbẹni Okechukwu Ode lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, nigba to bara ẹ nile-ẹjọ Majisreeti ipinlẹ Eko, nibi ti wọn ti fẹsun kan an pe oun ati ọrẹ rẹ jale, ẹja panla gbigbẹ miliọnu mẹta ataabọ Naira (N3.6 million) ni wọn ji gbe.

Ode, ẹni ọgbọn ọdun ati Ọgbẹni Chukwudi Ojukwu toun jẹ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ni wọn fẹsun mẹta ọtọọtọ kan ni kootu ọhun. Wọn ni wọn gbimọ-pọ lati huwa buruku, wọn si tun gbabọde fun ole.

Abilekọ Joy Odoh to fẹsun kan wọn ni ọmọọṣẹ oun tẹlẹ ni Chukwudi ni tiẹ, o lo pẹ to ti n ba oun taja ni ṣọọbu oun to wa ni Opopona Market, l’Ebute-Mẹta, koun too le e danu lọdun to kọja (2019) nigba ti awo ya pe afurasi ọdaran naa n fẹwọ.

O ni ibi toun ti kọkọ fura ni pe ojoojumọ lowo ọja to n ba oun ta ki i pe, niṣe lowo maa n din tawọn ba ti n ṣiro owo lalẹ, ọrọ kantan-kantan lo si maa n sọ, ki i ri alaye gidi kan ṣe.

Igbẹyin-gbẹyin laṣiiri ẹ waa tu soun lọwọ pe o ti lọọ ṣe ẹda awọn kọkọrọ ṣọọbu oun sọwọ, to jẹ pe aago meji oru lẹyin tawọn ba ti lọ sile lo maa n waa ji panla oun ko.

Obinrin naa lawọn sikiọriti ti wọn n ṣọ agbegbe ti ṣọọbu naa wa ko fura si i rara, tori wọn ti mọ ọn daadaa, wọn lo maa n sọ pe oun gbagbe ẹru kọsitọma si ṣọọbu ni.

Ṣugbọn lẹyin toun ti le e danu ni Chukwudi ati Ode tun lọọ lẹdi apo pọ, ti wọn si fọ ṣọọbu naa loru ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa, to kọja yii, iyẹn ọjọ Aje to lọ lọhun-un, gẹgẹ bo ṣe wi.

Agbefọba, Inspẹkitọ Kẹhinde Ọlatunde, ni iwadii awọn fihan pe niṣe lawọn afurasi tọwọ ba naa, atawọn kan tawọn ọlọpaa ṣi n wa lọwọ, diidi mu mọto lọọ fọ ṣọọbu ọga Chukwudi ni nnkan bii aago meji aabọ oru ọjọ Aje ọhun, ti wọn si ko awọn apo repẹtẹ ti ẹja panla kun inu rẹ ti iye wọn jẹ miliọnu mẹta aabọ Naira.

Wọn ni panla ẹlẹgbẹrun mẹrinlelogun Naira (N24,000) pere ni Okechukwu Ode jẹwọ pe oun ra ninu ọja ti wọn ji gbe naa, o loun ko tiẹ mọ pe ẹru ole ni wọn waa ta foun.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ọhun ni wọn lo ta ko isọri okoolenirinwo o din mẹsan-an (411), okoodinlọọọdunrun ati meje (287), ati okoolelọọọdunrun ati mẹjọ (328) iwe ofin iwa ọdaran tọdun 2015 tipinlẹ Eko n lo.

Bi Okechukwu ṣe bọọlẹ ninu ọkọ ẹlẹwọn ti wọn fi gbe wọn wa to ri i pe kootu lawọn balẹ si lo bu sẹkun gbaragada, to si n yira mọlẹ.

Ninu ọrọ abamọ to n sọ pẹlu omije, o loun ko mọ mọwọ- mẹsẹ nipa ọrọ jiji panla, ati pe alailara loun, latọjọ tawọn agbofinro ti gbe oun sọ sahaamọ, ko sẹni to beere oun, ti wọn ba si ṣe bayii ran oun lẹwọn, aye oun ti bajẹ niyẹn.

Agbẹjọro Tunde Idris to gba lati duro fawọn olujẹjọ naa bẹbẹ pe kile-ẹjọ faaye beeli silẹ fun wọn.

Adajọ Abilekọ A. O. Kusanu faaye beeli ẹgbẹrun lọna igba Naira silẹ fẹnikọọkan pẹlu oniduuro meji meji, ti wọn gbọdọ ni iwe-ẹri owo-ori ọdun mẹta ti wọn ti san sapo ijọba ipinlẹ Eko, ki wọn si ni awọn dukia ti ko jinna si agbegbe kootu ọhun.

O ni titi di ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ti igbẹjọ mi-in maa waye, ki wọn ṣi lọọ fi awọn afurasi aji-panla ọhun pamọ sọgba ẹwọn Kirikiri.

Leave a Reply