*Idi abajọ ree o
Ninu oṣu kẹta, lọdun 1979, ipolongo ibo n gbona lalaala laarin awọn ẹgbẹ oṣelu maraarun tijọba fọwọ si. Kaluku lo n ṣe ki iyọ dun toun, kaluku lo si n wa gbogbo ọna lati fi wọle ijọba lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ọdun naa, nigba to jẹ ọjọ ti awọn ijọba ologun labẹ Ọgagun agba Oluṣẹgun Ọbasanjọ da pe awọn yoo gbejọba kalẹ fawọn alagbada niyẹn. Ẹgbẹ marun-un ti ja ogun ajaye, wọn si ti fi orukọ wọn silẹ, wọn ti ja ogun ajaye lọdọ ajọ to n ṣeto ibo igba naa ti wọn n pe ni FEDECO, wọn ti forukọ wọn silẹ ninu iwe idibo, wọn si ti kede orukọ yii fun gbogbo awọn ọmọ Naijiria pe awọn ẹgbẹ marun-un ti wọn fẹẹ dupo lasiko ibo ree. Ninu awọn maraarun-un ni wọn yoo si ti yọ aarẹ Naijiria tuntun jade. Awọn ẹgbẹ naa ni GNPP, NPN, NPP, PRP ati UPN. Wọn ti ṣedanwo, wọn n reti ọjọ tawọn araalu yoo fun wọn lesi idanwo wọn.
Ọkunrin olowo kan lati ilẹ Hausa ti wọn n pe ni Waziri Ibrahim lo n dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ GNPP. Alaaji ni. Alaaji naa lẹni to fẹẹ du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ NPN, Shehu Shagari ni wọn n pe e, lara awọn ọmọlẹyin Sardauna Ahamadu Bello ni, idi si niyi to jẹ gbogbo awọn ti wọn jẹ ọmọlẹyin aṣaaju awọn oloṣelu ilẹ Hausa naa ni wọn wa lẹyin Shagari, ati diẹ ninu awọn olowo ati alagbara ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo. Nnmadi Azikiwe, aarẹ Naijiria nigba kan loun, oloṣelu atijọ ti orukọ rẹ si ti milẹ kaakiri Naijiria tẹlẹ ni, oun lawọn NPP fa kalẹ, wọn ni ko du ipo aarẹ lorukọ wọn. Aminu Kano naa wa ninu awọn oloṣelu atijọ, bo tilẹ jẹ gbogbo igbokegbodo rẹ laarin awọn oloṣelu ati mẹkunnu ilu Kano lo mọ. Sibẹ naa, eeyan nla kan ni ni gbogbo agbegbe naa, oun lo si da ẹgbẹ PRP silẹ, oun naa ni wọn si ni ko dupo aarẹ lorukọ gbogbo wọn.
Ni ti ẹgbẹ UPN, Ọbafẹmi Awolọwọ lawọn mu, ki i ṣe nitori pe oun naa lo da ẹgbẹ UPN silẹ nikan, ṣugbọn nitori pe ko tun si olorukọ mi-in to to o laarin awọn ti wọn jọ wa ninu ẹgbẹ naa, bẹẹ ni ninu awọn ti wọn wa ninu ẹgbẹ oṣelu mi-in, ti a ba ti yọwọ Azikiwe kuro, ko tun sẹni to sun mọ Awolọwọ ninu orukọ. Lati ilẹ yii wọ oke-okun, ko si ibi ti wọn ko ti mọ ọn, ohun kan ti wọn si mọ ọn fun to yatọ si tawọn to ku naa ni pe ko si ẹni to le ṣejọba daadaa ju u lọ ninu gbogbo awọn ti wọn fa ara wọn sita pe ki wọn dibo fawọn yii, awọn eeyan mọ pe Awolọwọ nikan lo le ṣe ohun ti awọn n fẹ fawọn. Nitori eyi lo ṣe jẹ pe ko si ẹni ti ariwo tabi okiki rẹ pọ to ti Awolọwọ yii ninu gbogbo awọn to ku, ibi yoowu to ba gbe kampeeni rẹ lọ, ero yoo maa wọ bii omi tọ ọ lẹyin ni. Ṣugbọn awọn alagbara ko fẹ eyi rara.
Loootọ ni awọn ṣọja fẹẹ gbejọba silẹ, ṣugbọn wọn ko fẹ ẹni ti yoo pada fun awọn ni wahala kankan, ẹni ti yoo yẹ iṣẹ ti awọn ti ṣe sẹyin wo, ẹni ti yoo maa beere awọn owo kan to sọnu ati ọna to gba sọnu ati ẹni to sọnu mọ lọwọ. Lọrọ kan, awọn ko fẹ ẹni ti yoo tu idi awọn wo rara. Wọn mọ pe to ba jẹ Great Nigeria People’s Party (GNPP), lo wọle, Alaaji Waziri Ibrahim ti i ṣe olori ẹgbẹ naa ko ni i wadii ẹnikan wo, nitori ọdọ awọn ologun loun naa ti ri owo to n na bayii, kọntirakitọ wọn ni, bo ba si fẹẹ tu idi ṣọja wo, bii ẹni to n tu idi ara rẹ sita ni. Ni ti NPN, National Party of Nigeria, ẹgbẹ awọn alagbara gidi ni, ko si si ikowojẹ tabi iwa ibajẹ kan to lọ ni Naijiria to ṣẹyin ọpọlọpọ awọn ti wọn da ẹgbẹ yii silẹ, nitori bẹẹ, ko sẹni ti yoo wadii ẹnikan ninu wọn, ọkan kaluku ni yoo si balẹ pe, ni ti Alaaji Shehu Shagari, ko ni i si ewu lẹgbẹrin ẹkọ.
Ki i ṣe oni, ki i ṣe ana, ti awọn oloṣelu ati awọn ologun Naijiria ti mọ Oloye Nnamdi Azikiwe pe ko ni i di ẹnikan lọwọ, bo ba wọle ibo labẹ asia ẹgbẹ Nigeria People’s Party, ibi ti aye ba tẹ si ni yoo tẹ si, ohun tawọn ti wọn lagbara ninu ijọba ologun ati ijọba to ba ti wa tẹlẹ ba ni ko ṣe naa ni yoo ṣe. Wọn mọ pe ariwo ti Azikiwe yoo maa pa ni pe ki ilu ṣaa ti ma bajẹ lori oun, ko si ni i fọwọ kan awọn yoowu ti wọn ba kowo jẹ tabi ti wọn huwa ibajẹ kankan. Ẹni kan tawọn eeyan naa tun bẹru diẹ ni Alaaji Aminu Kano, ti ẹgbẹ People’s Redemption Party (PRP), wọn mọ pe alakatakiti ni, wọn mọ pe awọn talaka lo maa n pariwo pe oun n ja fun, bi ọwọ rẹ ba si ba ijọba loootọ, o le foju awọn ọlọla ati olowo ri mabo. Ṣugbọn ọkan awọn eeyan naa balẹ fun kinni kan, iyẹn ni pe ko si ọna ti Aminu Kano yoo fi wọle ibo naa, koda ki wọn di i lẹẹmẹjọ.
Ẹni kan ṣoṣo ni wọn mọ pe ọrọ rẹ lẹwu pupọ ninu awọn ti wọn fẹẹ du ipo aarẹ yii, iyẹn naa ni Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ. Wọn mọ pe Awolọwọ nikan lo daju ju lọ pe o le bori ninu ibo ti wọn fẹẹ di naa, nitori oun lawọn eeyan fẹran ju lọ, o lero lẹyin pupọ ju, gbogbo awọn mẹkunnu lo si jọ pe wọn fẹ ko waa ṣejọba awọn. Ohun to tun da wọn loju tadaa ni pe wọn mọ pe bi Awolọwọ ba wọle, ko si ẹni to le sọ ọ ti ko ni i tudii awọn ti wọn ba kowo jẹ, ko sẹni to le sọ ọ ti ko ni i yẹ awọn ijọba to ti re kọja lọ wo, ko si wo awọn ibajẹ ti wọn ṣe lati fi mu wọn. Nigba ti wọn yoo pari ọrọ naa, wọn ni Awolọwọ ki i dari jiiyan: to ba wọle, ki gbogbo awọn ti wọn ti ṣe e ni aburu ri ma ṣafara ni o, gbogbo wọn ni yoo jiya ẹṣẹ wọn. Nidii eyi ni gbogbo wọn ṣe panu pọ, pe bi awọn ko ba fẹẹ tẹ, ti awọn ko si fẹẹ kan abuku, ti awọn ko si fẹ ki aṣiri awọn tu, gbogbo awọn lawọn gbọdọ ri i pe Awolọwọ ko gbajọba Naijiria losu kẹwaa, 1979.
Bi awo ṣe n lu, bẹẹ naa ni awo n gbọ; awọn ti wọn mọ Awolọwọ daadaa, ti wọn si tun mọ lara awọn alatako ti wọn wa nidii erokero yii pada waa sọ fun un pe ko maa sọ nibi to ba ti n kampeeni, pe oun ko ni i wadii ẹnikan wo, oun ko si ni i tudii wọn, ohun to re kọja ti re kọja lọ. Awolọwọ gbiyanju lati sọrọ naa, ṣugbọn awọn oloṣelu yii ko gba a gbọ, paripari rẹ si ni pe ko jọ pe oun alara gba ara rẹ gbọ pe oun ko ni i beere owo ti awọn eeyan yii ji ko lọwọ wọn. Nibi ti ikunsinu si ti wa laarin awọn alagbara wọnyi si Awolọwọ niyẹn, ni wọn ba bẹrẹ si i wa gbogbo ọna lati ta abuku rẹ, ati lati sọ fawọn eeyan pe o n tan wọn ni, ko ni i ṣe ohun to ba loun yoo ṣe fun wọn fun wọn. Nigba naa, awọn agbalagba oloṣelu ti wọn ti mọ Awolọwọ lati ọjọ to pẹ ko le jade lati bu u tabi lati tabuku rẹ, awọn ọmọde olowo nikan ni wọn n jade.
Lara awọn ọdọ ti owo wa lọwọ wọn nigba naa ni Moshood Kashimaawo Abiọla, nitori pe oun ni alaga ẹgbẹ NPN ni ipinlẹ Ogun, to si jẹ ipinlẹ Ogun yii naa ni Awolọwọ ti wa, oun ni wọn ti ṣaaju lati maa ta ko Awolọwọ nibikibi, tabi boya oun lo si ti ara rẹ ṣaaju lati maa fi han awọn eeyan pe oun ko bẹru, ati pe ko si kinni kan ti yoo ṣẹlẹ, oun yoo ri i pe ẹgbẹ oun, NPN, gba ipinlẹ Ogun lọwọ Awolọwọ lasiko ti wọn ba dibo naa tan. Ṣugbọn lẹẹkan naa lọrọ yii pada kuro ni ọrọ ija NPN ati UPN, o kuku yi si ọrọ ija Abiọla atawọn eeyan tirẹ pẹlu Awolọwọ atawọn ọmọlẹyin rẹ gbogbo. Abiọla naa lo si da a silẹ o. Awolọwọ lo n ṣe ipolongo ibo bi oṣu kẹta ọdun ti n pari lọ, lo ni bi ẹgbẹ UPN ba fi le wọle ti awọn si gbajọba lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, 1979, ijọba naa yoo bẹrẹ si i san Igba, iyẹn ọgọrun-un meji, Naira fun oṣiṣẹ ti owo rẹ kere ju lọ lẹnu iṣẹ ọba. O ni awọn oṣiṣe yoo bọ saye bawọn ba gbajọba, N200 lowo-oṣu wọn.
Ọro yii lo jo Abiọla ati awọn NPN to ku lara, ni Abiọla ba sare pe awọn oniroyin jọ, o ni ki wọn waa gbọ o, irọ buruku l’Awolọwọ n pa.
Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.