Baba Gomina Kwara, AbdulGaniyu Abdul-Razaq, jade laye lẹni ọdun mẹtalelaaadọrun-un

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Laaarọ ọjọ Abamẹta, Satidee, yii, ni ẹbi Abdulrazaq kede iku baba Gomina Kwara, Alaaji AbdulGaniyu Fọlọrunṣhọ Abdul-Razaq SAN (OFR), ẹni to jade laye lẹni ọdun mẹtalelaaadọrun-un.

Atẹjade ti aṣoju mọlẹbi naa, Dokita Alimi Abdulrazaq, gbe sita ṣalaye pe nnkan bii aago meji oru ọjọ Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keje, ọdun yii lo dakẹ niluu Abuja.

 

Oloogbe naa to jẹ Mutawali tilu Ilọrin ati Tafida ti Zazzau (Zaria), ni agbẹjọro akọkọ lẹkun Arewa orileede Naijiria.

O fi iyawo, ẹni aadọrun-un ọdun, Alaaja Raliat AbdulRazaq, awọn ọmọ ati ọmọọmọ silẹ saye lọ. Lara wọn ni Gomina Abdulrahman Abdulrazaq.

 

Mọlẹbi ti lawọn yoo kede eto isinku rẹ laipẹ.

 

Leave a Reply