Baba ọgọta ọdun dero ẹwọn l’Ọyọọ, ọmọọdun mẹrinla lo fipa ba lo pọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori to fipa ba ọmọọdun mẹrinla laṣepọ, ile-ẹjọ ti sọ baba ẹni ọgọta (60) ọdun kan, Badru Ajadi, sahaamọ ọgba ẹwọn.

Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keji, oṣu kẹjọ, ọdun 2021 yii, nigbẹjọ ọhun waye nile-ẹjọ Majisreeti to wa niluu Ọyọ.

 

Ni nnkan bii aago meje alẹ Ọjọruu to kọja, iyẹn Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keje, ọdun yii, ni baba agba yii huwa agbaaya ọhun.

Gẹgẹ bi agbefọba to gbe e lọ si kootu ṣe ṣalaye niwaju adajọ, o ni Ajadi, ẹni to n gbe Aba Alade, nitosi Ọlọrunṣogo, n’Ibadan, fọgbọn buruku tan ọmọdebinrin naa to jẹ ọmọ alabaagbe rẹ wọnu yara ẹ, to si ko ibasun fun un.

Awọn obi ọmọbinrin ọhun ni wọn fọlọpaa mu alabaagbe wọn yii lẹyin ti ọmọ wọn dele royin ohun ti baba agbaaya naa foju ẹ ri fun wọn.

Lẹyin ti wọn fi ẹsun ifipabanilopọ kan Ajadi, adajọ kootu ọhun, Onidaajọ S.H. Adebisi, ko faaye silẹ lati gbọ awijare olujẹjọ to fi sun igbẹjọ naa si ọgbọnjọ, oṣu kẹjọ yii, nigba ti igbagbọ wa pe eto yoo ti pari lori kootu mi-in to ṣee ṣe ki wọn ti gbọ ẹjọ naa nitori ile-ẹjọ ẹ yii ko lẹtọọ lati gbọ ọ.

Onidaajọ Adebisi waa paṣẹ fawọn agbofinro lati fi baba naa pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn Abolongo, niluu Ọyọ, titi digba ti igbẹjọ ọhun yoo tun maa waye ni kootu mi-in.

Leave a Reply