Baba ọmọ Flakky yi oun pada:Ija lo de torin dowe, emi ni mo ni ọmọ ti Ronkẹ Odusanya bi

Ọrọ bẹyin yọ lọsẹ to kọja yii, nigba ti Aranmọlate Saheed Ọlanrewaju, ọkunrin ti ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Ronkẹ Odusanya ti gbogbo eeyan mọ si Flakky Ididowo, bimọ fun, gbe fidio kan jade, nibi to ti ni oun tọrọ idaraiji lori bi oun ṣe lọ sile-ẹjọ lati sọ fun kootu pe ọmọ ti Ronkẹ bi ki i ṣe ọmọ oun, ati pe ki kootu jẹ ki awọn ṣe ayẹwo ẹjẹ lati fi idi ẹni to ni ọmọ naa mulẹ, o ni aṣiṣe ni, ati pe ọmọ oun ni ọmọbinrin ti Ronkẹ bi ti wọn sọ ni Oluwafifẹhanmi Arọmọlatẹ naa.

Ninu fidio ọhun ni ọkunrin ti wọn n pe ni Jago yii ti ṣalaye pe, ‘‘Orukọ mi ni Aranmọlatẹ Saidi Ọlanrewaju. Mo n lo fidio ti mo ṣe yii lati ṣalaye lori ayẹwo ẹjẹ ti wọn n pe ni DNA ti mo beere fun nile-ẹjọ. Mo tọrọ aforiji lori eleyii, mo si fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe Oluwafifẹhanmi Aranmọlatẹ jẹ ọmọ mi, mo si nifẹẹ rẹ gidigidi tọkantọkan mi. Ija lo de lorin dowe o. Mo tọrọ aforiji pe mo beere fun ayẹwo ẹjẹ nipa rẹ.’’

 

 

 

Tẹ o ba gbagbe,  lọdun to kọja ni Flakky Ididowo pẹlu ọkọ ẹ, Ọlanrewaju Saheed, ti inagijẹ rẹ n jẹ Jago yii gbera wọn lọ sile-ẹjọ Majisreeti to wa ni Kootu kẹjọ, Samuel Ilọri Court House, ni Ọgba, nipinlẹ Eko, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun to kọja, pe afi kawọn onimọ iṣegun ba tọkọ-taya naa fi imọ ẹrọ yẹ ẹ wo lati mọ ẹni to jẹ baba ọmọbinrin ti wọn lawọn bi ọhun, Oluwafifẹhanmi.

Jago lo sọ nile-ẹjọ nigba ti igbẹjọ n lọ lori ọrọ wọn pe koun too le sọrọ lori itọju ati gbigbọ bukaata lori ọmọ naa, afi koun kọkọ ri aridaju pe ọmọ oun lọmọbinrin yii loootọ, o loun fẹ kile-ẹjọ faṣẹ si i lati lọọ ṣe ayẹwo tawọn eleebo n pe ni DNA (Deoxyribonucleic Acid), fun un.

 

 

Kẹmika DNA yii lo maa n ṣe ifọsiwẹwẹ awọn eroja to wa lara ọmọ ati ti obi, o si maa n fi iyatọ ati ijọra han laarin obi ati ọmọ, debii pe kedere lo maa han to ba jẹ eroja iya ati baba papọ pẹlu tọmọ ti wọn n jiyan le lori, paapaa ju lọ ti baba. Bi ko ba si papọ, afi kiyaa ọmọ naa tete ṣalaye ibi to ti royun he, ko si jẹwọ baba ọmọ gan-an.

Lọpọ igba, bi ariyanjiyan ba waye lori ẹni to jẹ baba ọmọ gan-an, tabi ti baba ọmọ ba n fura pe afaimọ ni ko ma jẹ ọmọ ale niyawo oun pe lọmọ oun, ni ibeere fun iru ayẹwo akanṣe yii maa n waye.

 

 

Iru ayẹwo yii ki ṣe ọrọ inawo kekere rara, tori ẹ, niṣe ni Ronkẹ ati lọọya rẹ beere pe ta lo fẹẹ sanwo ayẹwo ọhun, ile-ẹjọ si paṣẹ pe Ọgbẹni Saheed to beere fun un ni ko bojuto inawo to ba tidi ẹ yọ.

Ronkẹ tun rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ pe ọsibitu ti awọn agbofinro ti maa raaye mojuto bi nnkan ba ṣe n lọ ni ki wọn ti ṣe ayẹwo naa, o ni ibi ti ko ti ni i saaye fun magomago kan ninu ẹ lo maa daa. Ile-ẹjọ si fọwọ si i bẹẹ, wọn ni kootu naa maa mojuto bi nnkan ba ṣe lọ si.

Adajọ-binrin M. O. Tanimọla paṣẹ pe ki wọn lọọ ṣayewo DNA ọmọ wọn ọhun ni ọsibitu kan ti wọn forukọ bo laṣiiri ni Lagos Island, ati pe taarata ni ileewosan naa maa fi abajade esi ayẹwo wọn ranṣẹ si ile-ẹjọ, ko maa baa si aaye fẹnikẹni lati ṣe magomago si esi naa.

Nibi ti wọn fẹnu ọrọ jona si niyi, ti wọn si n reti ki wọn fi ayẹwo ẹjẹ ranṣẹ si ile-ẹjọ ki igbẹjọ le tẹsiwaju. Afi bi wọn ṣe wa Jago ti, ti wọn ko gburoo ko lọọ ṣe ayẹwo ẹjẹ naa, ni wọn ba kede pe ijọba n wa ẹni ti Ronkẹ bimọ fun yii, iyẹn ni pe wọn dikilia wọntẹẹdi.

 

 

Ṣugbọn latọjọ ti igbẹjọ naa ti waye, niṣe ni wọn sọ pe Ọgbẹni Ọlanrewaju ti wọn ni ọmọ jayeyaye Eko ni gbọdọ sanwo ayẹwo ni wọn ni ọkunrin naa ti sa lọ patapata, nitori ko sẹni to gburoo rẹ, bẹẹ ni ayẹwo naa wa bẹẹ ti ko ṣe e.

Nigba ti kootu reti abọ ayẹwo titi ti wọn ko gburoo ọkọ Ronkẹ, wọn tun ranṣẹ pe e lọjọ kẹtala, oṣu kẹwaa, ọdun 2021, pe kawọn tun jokoo lori ẹjọ naa lẹẹkan si i, ṣugbọn Saheed ko tun wa.

O jọ pe eyi lo fa a ti ọkunrin naa fi jade sita, to si fi ṣe fidio pe oun ko nilo ayẹwo ẹjẹ mọ, o ni oun loun ni ọmọbinrin ti wọn sọ ni Fareedah Oluwafifehanmi Aranmọlatẹ yii. Bẹẹ lo pari ọrọ rẹ pe oun nifẹẹ ọmọ naa, ati pe ija lo de ti orin dowe lọrọ ọhun.

Ṣugbọn ọpọ awọn ti wọn ka ọrọ naa ni wọn n sọ pe afi ko lọọ tọrọ aforiji lọwọ Ronkẹ Odusanya nitori ẹsin ati abuku to fi ọrọ naa ko ba a.

 

 

Bakan naa lawọn kan sọ pe awọn ti mọ pe o kan fẹẹ fi owo rẹ ṣofo ni tẹlẹ pẹlu ayẹwo ẹjẹ to ni oun fẹẹ ṣe nitori afọju gan-an mọ pe oun ni ọmọ naa jọ.

Bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ọkunrin naa ko lẹbi nitori bo ṣe fẹẹ ṣe ayẹwo ẹjẹ ọmọ naa, wọn ni ọpọ aọn ọmọbinrin to wa nita bayii ko ṣee jẹrii rara.

Leave a Reply