O ma ṣe o! Baba Suwe ti ku o

Faith Adebọla, Eko

Gbajugbaja adẹrin-in poṣonu nni, Babatunde Omidina, tawọn eeyan mọ si Baba Suwe ti jade laye.
Ọmọ bibi oloogbe naa, Adeṣọla Omidina, kede iku baba rẹ lori ikanni ayelujara Instagiraamu rẹ lọjọ Aje, Mọnde ọjọ kejilelogun oṣu kọkanla yii pe:
“Eyi ni lati kede iku airotẹlẹ to pa Baba mi, Ọgbẹni Babatunde Nurudeen Omidina, irawọ oṣere ti o lẹgbẹ, tawọn eeyan mọ si ‘Baba Suwe’.
Alaye lẹkun-unrẹrẹ nipa eto isinku rẹ yoo waye laipẹ.
Sun un re o, Dadi mi.”
A gbọ pe nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Aje yii lọkunrin naa mi eemi ikẹyin lẹyin ọpọ ọdun ti aisan ti da a gbalẹ, ti ko si le kopa ninu ere tiata bo ṣe maa n ṣe mọ.
Baba Suwe ni ọkọ oloogbe Mọnsurat Omidina, tawọn eeyan mọ si Mọladun Kẹnkẹlẹwu, toun naa jẹ ọjafara alawada, ko too jade laye.
Ọjọ kejidinlogun oṣu kẹjọ ọdun 1958 ni wọn bi Baba Suwe, ẹni ọdun mẹtalelọgọta (63) lo doloogbe.

Leave a Reply