Babalawo ati Lukman kun Oyindamọla si wẹwẹ, ẹgbẹrun lọna ọgọrin Naira ni wọn ta ẹsẹ ati ọkan rẹ fawọn to fẹẹ fi ṣetutu owo

Gbenga Amos, Abẹokuta

Ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Ogun ti tẹ tọkọ-taya kan, Taiwo Otufẹsẹ Ajalọrun ati Salawa Oyenusi, pẹlu awọn mẹfa mi-in,  Lukman Ọladele, Kayọde Ibrahim, Bello Akeem, Alebioṣu Adebayọ, Fatai Rasheed ati Fatai Jimoh, ti wọn ka ẹya ara eeyan ati ẹjẹ eeyan mọ lọwọ.

Ọmọbinrin kan, Oyindamọla Akinyẹmi, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, lawọn olubi ẹda naa pa, ti wọn si kun ẹya ara rẹ si wẹwẹ, ni wọn ba n ge e ta bii ẹran maaluu.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, fi lede lori iṣẹlẹ naa to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti ṣalaye pe ọmọbinrin kan, Ojo Ọmọlara, lo lọ si agọ ọlọpaa Ọbalende, to wa ni Ijẹbu-Ode, lati fi to wọn leti pe oun ko ri alajọgbele oun, Oyindamọla Akinyẹmi, to jade nile laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun to kọja, ṣugbọn ti ko pada sile, gbogbo bi oun si ṣe n pe foonu rẹ ni ko lọ, nitori o ti wa ni pipa. Ṣugbọn awọn ọlọpaa ni ko ṣi ni suuru ki iṣẹlẹ naa fi pe wakati mẹrinlelogun ki awọn too le ṣe ohunkohun si i gẹgẹ bi ofin ṣe la a silẹ, nitori o ṣee ṣe ko ṣi pada wa sile laarin asiko naa.

Lasiko ti awọn ọlọpaa yii n yide kaakiri lọjọ keji, iyẹn ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun to kọja yii, ni wọn ri oku eeyan kan ti wọn ti ge awọn ẹya ara rẹ kan lọ loju ọna. Awọn agbofinro ọhun gbe oku naa lọ si mọṣuaari, wọn si bẹrẹ iwadii lori rẹ lẹsẹkẹsẹ.

Mọṣuari ti wọn gbe oku yii lọ ko jinna si ile ti Oyindamọla ti wọn n wa yii n gbe. Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ mọṣuari yii lo pe awọn mọlẹbi obinrin naa lati waa wo oku ti wọn gbe wa sọdọ wọn boya ẹni ti wọn n wa ni.

ALAROYE gbọ pe alajọgbele awọn obinrin yii, iyẹn Ọmọlara wa ninu awọn to lọọ wo oku naa, oju-ẹsẹ lo si sọ fun wọn pe obinrin to jade ti ko pada wọle naa ni. Awọtẹlẹ rẹ ni obinrin yii fi da a mọ gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe wi, nitori wọn ti ge ori rẹ lọ.

Aṣiri yii lo jẹ ki DPO Ọbalende, Murphy Salami, ko awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa sodi, ti wọn si bẹrẹ iwadii lati tuṣu desalẹ ikoko nipa awọn to ṣiṣẹ buruku naa.

Iwadii wọn so eeso rere pẹlu bi wọn ṣe mu babalawo kan, Taiwo Otufẹsẹ Ajalọrun, nigba ti Ọlọrun yoo si tu aṣiri rẹ patapata, wọn ba foonu itel obinrin ti wọn pa yii lọwọ rẹ.

Oju-ẹsẹ ni awọn agbofinro mu un, ti wọn si lọọ ṣe ayẹwo inu ile rẹ. Nibẹ ni wọn ti ba ike kan to kun fun ẹjẹ, ẹjẹ naa si jẹ ti Oyindamọla ti wọn pa yii.

Mimu ti wọn mu un lo ṣe okunfa bi wọn ṣe mu ọrẹ rẹ kan, Lukman Ọladele, ti wọn si ba ẹsẹ obinrin to ti bimọ meji naa nile rẹ. Lasiko ti awọn ọlọpaa n fọrọ po wọn nifun pọ ni wọn jẹwọ ẹni to maa n ra ẹya ara eeyan naa lọwọ wọn.

Awọn eeyan naa jẹwọ pe awọn, iyẹn Taiwo Otufẹsẹ Ajalọrun ati Lukman pe ile Lukman to jẹ ale ọmọbinrin yii ni wọn tan Oyindamọla lọ. Bo si ti debẹ ni Taiwo ati Lukman fun un lọrun pa. Bi wọn ṣe pa a tan ni wọn ti kun un si wẹwẹ, wọn ge ori rẹ sọtọ, wọn ge ẹsẹ ati ọwọ rẹ mejeeiji, wọn si ta a fawọn to maa n fi ẹya ara eeyan ṣowo ti wọn ti n duro lati ra a.

Ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira ni wọn ta ẹsẹ kọọkan, wọn ta ọkan rẹ ni ẹgbẹrun lọna aadọta Naira fun ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Akeem Bello, ṣugbọn wọn ni ẹni to ra ori obinrin naa ti sa lọ, wọn ṣi n wa a di ba a ṣe n kọ iroyin yii.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki wọn ko aọn ọdaran naa lọ si ẹka ileesẹ ọtelẹmuyẹ to n ṣewadii iwa ọdara fun iwadii to jinnlẹ lori ọrọ naa.

 

Leave a Reply