Babalawo to ni Iyabọ Ojo maa ku lori ọrọ Baba Ijẹṣa ti ku o

Faith Adebọla, Eko

Bo ba jẹ pe wọn ṣe oogun madarikan fun gbajugbaja oṣere ilẹ wa, Iyabọ Ojo, ni, a jẹ pe ojulowo oogun ni wọn ṣe fun un, bo ba si jẹ ori tawọn kan maa n kọ pe ‘ẹni ba pe n ku aa ṣaaju mi ku’ ni Iyabọ n kọ, a jẹ pe orin naa ṣiṣẹ fun un, latari bi wọn ṣe ni babalawo kan to sọ aṣọtẹlẹ lodi si obinrin oṣere naa pe o maa ku lori ọrọ Baba Ijẹṣa, wọn ni babalawo naa ti dagbere faye lojiji.

Ba a ṣe gbọ, ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii ni wọn lọkunrun naa jade laye, wọn ni baba naa ko ṣaarẹ kan, ojiji ni iku naa waye.

Nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni fidio kan gori ẹrọ ayelujara, nibi ti babalawo ọhun ti n ṣepe fun Iyabọ Ojo, o ni tiẹ ti pọ ju lori ọrọ Ọlanrewaju Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa yii.

Babalawo naa sọ pe “ẹ ma da Iyabọ Ojo yẹn, abi ki lo pe’ra ẹ, lohun, ko sohun to maa gbẹyin ọrọ yii fun un ti ko ba jawọ lọrọ Baba Ijẹṣa, he would suffer and die (o maa laalaṣi, o si maa ku ni). Tori Baba Ijẹṣa o sẹtuu (settle) ẹ, ati obinrin ekeji ẹ (Damilọla Adekọya, “Princess”) lo n jẹ ko maa ṣe bo ṣe n ṣe yẹn.

‘’Ki le jẹ gan-an, ko ja mọ nnkan, toto (abẹ) lo n ta kaakiri. To ba n lọ Abuja foroforo lẹẹmẹwaa, ki lo n lọọ ṣe nibẹ, ṣebi abẹ lo n lọọ ta. Ki lo waa jokoo ti ọrọ ọlọrọ kankan-ankan si?”

Bayii lọkunrin to wọṣọ oogun abẹnugọngọ naa sọ ninu fidio ọhun.

Iyabọ Ojo naa fesi nigba naa, o ni buburu kan ko ni i ṣubu lu oun, ati pe ẹnikẹni to ba ro iku ro oun ni yoo ku.

Gbara ti iṣẹlẹ iku ojiji yii waye ni Iyabọ Ojo tun kọja sori ayelujara, lori ikanni Instagiraamu ẹ, o ni: “Ṣe ẹ ri i o, Yọmi Fabiyi ati gbogbo ẹyin eeyan buruku tẹ ẹ n sọpọọti iwa aidaa, tẹ ẹ n ditẹ mọ mi, tẹ ẹ fẹ ki n ja bọ, tẹ ẹ n gbero pe ki n ku, mo fẹ kẹ ẹ mọ nnkan kan pe, ẹyin igba lẹ n yin’gbado si, ẹ n fakoko ṣofo lasan ni.

“Ọlọrun nikan lo ni aṣẹ iku, oun lo le paayan to ba to asiko loju ẹ. Oun lo ni gbogbo ogo, emi o bẹru ọkunrin tabi obinrin kankan, bẹẹ ni mi o le dakẹ to ba dọrọ keeyan sọ otitọ.”

Leave a Reply