Babatunde kọ lu mọto onimọto latẹyin, o tun fibiinu pa dẹrẹba to wa a

Gbenga Amos, Ogun

 Gende ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Babatunde Adeyẹmi, ti wa lakolo awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, nibi to ti n geka abamọ jẹ latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o fi ọkọ ayọkẹlẹ jiipu rẹ kọ lu mọtọ onimọto loju popo latẹyin, eyi ti iba si fi bọọlẹ ko tọrọ aforiji tabi ko wa bo ṣe maa ṣatunṣe ọkọ to bajẹ, niṣe lo tun wakọ gori dẹrẹba to ni ọkọ to bajẹ, Ọgbẹni Ismail Ọbafunṣọ, lo ba fi mọto tẹ baba ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta naa pa, o si sa lọ raurau.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’Alaroye laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ, kẹtalelogun, oṣu yii, pe ni nnkan bii aago mẹjọ kọja iṣẹju diẹ lalẹ ọjọ kẹjọ, oṣu Kejila, ọdun 2022 yii, ni iṣẹlẹ aburu naa waye.

Babatunde ni wọn lo wa jiipu Lexus ti wọn kọ nọmba akanṣe “Olu of Ọya” si lara ọhun, o si kọ lu ọkọ ayọkẹlẹ to wa niwaju rẹ, eyi ti Ismail wa, latẹyin, ṣugbọn akọlu naa ko pọ rara, wọn niṣe ni paanu ọkọ naa tẹ wọnu diẹ.

Ismail bọọlẹ lati wo jamba to ṣẹlẹ si mọto rẹ, o si reti pe ki ẹni to wakọ kọ lu oun naa bọọlẹ wo ohun to ṣẹlẹ, ṣugbọn Babatunde ko kuro lori ijokoo awakọ to wa, ko si pana ọkọ rẹ.

Eyi lo mu ki Ismail lọọ ba a pe ko bọọlẹ waa wo akọlu to ṣẹlẹ, ṣugbọn ọkunrin naa taku, ko bọọlẹ, ko si kaaanu baba agbalagba to ba mọto rẹ jẹ ọhun.

Iwa ọta aje ti Babatunde hu yii lo mu ki Ismail fura pa afaimọ ni ki i ṣe pe o fẹẹ dọgbọn sa lọ ni, lo ba lọọ jokoo siwaju ọkọ rẹ, iyẹn lori bọnẹẹti ọkọ, o loun o ni i kuro nibẹ, afi ti Babatunde ba bọọlẹ, to si ṣatunṣe si mọto oun to bajẹ.

Nigba ti Babatunde ri eyi, wọn lo o bọọlẹ, ṣugbọn ki i ṣe  lati wo mọto to bajẹ o, ko si sọrọ nipa atunṣe kankan, niṣe lo lọọ kilọ fun Ismail pe ko yara kuro lori bọnẹẹti ọkọ oun, tori ti ko ba kuro, oun maa fi mọto pa a danu ni, tabi koun wa a lọ tefetefe, bẹẹ ni wọn lo leri mọ baba agbalagba naa.

Baba yii ko kuro lori bọnẹẹti ọhun, o ni ara to ba wu Babatunde ko da, ni Babatunde ba fibinu ko sinu jiipu rẹ, o ṣana sọkọ, o si ki ere mọlẹ debi ti baba ọhun fi re bọ, lo ba fi jiipu gori ẹ. Nibi tibinu naa ru bo o loju de, wọn ni lẹyin to ti gori baba naa tan, o tun fi ọkọ rẹ si rifaasi, o si tun tẹ baba naa mọlẹ latẹpa, lati ri i pe oun pa a ku patapata. Lẹyin eyi lo tẹna ọkọ ọhun gidi, o sa lọ.

Ṣugbọn ma ṣe e loogun ma mọ, awọn tọrọ ọhun ṣoju rẹ atawọn mọlẹbi oloogbe lo lọọ fẹjọ sun ọlọpaa, lawọn ọtẹlẹmuyẹ ba bẹrẹ si i wa afurasi ọdaran yii, ati ọkọ “Olu of Ọya”, to fi pa baba naa. Lẹyin ti wọn fimu finlẹ daadaa, wọn tọpasẹ Babatunde de ile baba rẹ to wa laduugbo Kemta, Idi-Aba, l’Abẹokuta, ibẹ lawọn agbofinro ka a mọ, ti wọn si mu un, atoun ati mọto ba dero ahamọ.

Ẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran abẹle lolu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa l’Eleweẹran, l’Abẹokuta, ni Babatunde wa bayii, gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankọle, ṣe paṣẹ. Ibẹ lo ti n ṣalaye ohun to jẹ yo to fi fibinu pa ẹni ẹlẹni. Wọn ni tiwadii ba ti pari, ile-ẹjọ ni wọn yoo taari afurasi apaayan yii si laipẹ.

Leave a Reply