Banki apapọ paṣẹ fawọn araalu ati ileefowopamọ: Ẹ maa gba owo atijọ lọwọ onibaara

Adewumi Adegoke

Banki apapọ ilẹ wa, Central Bank of Nigeria (CBN), ti paṣẹ pe ki awọn araalu maa gba ẹgbẹrun kan ati aadọta Naira owo atijọ ti wọn ti fofin de tẹlẹ pe ko ni i jẹ nina mọ.

Agbẹnusọ fun banki apapọ ilẹ wa naa, Isa Abdulmumin, lo fi ikede yii sita. O ni owo naa ti di ohun to bofin mu lati maa na pẹlu idajọ ile-ẹjọ giga ilẹ wa to paṣẹ pe ki awọn araalu ṣi maa na owo naa titi ọjọ to gbẹyin ninu oṣu Kejila, ọdun yii, ti opin yoo de ba lilo owo naa fun kata-kara.

O waa paṣẹ fun awọn banki kaakiri ilẹ wa lati maa gba owo yii lọwọ awọn ti wọn ba ko o wa, beẹ ni ki wọn ko o si awọn ẹnu ẹrọ ipọwo wọn (ATM), fun awọn araalu lati na.

O ni bo tilẹ jẹ pe banki apapọ ilẹ wa ko ti i sọ ohunkohun lori owo atijọ naa, ṣugbọn ki awọn araalu maa na an lọ nitori aṣẹ ti kootu apapọ ilẹ wa ti pa.

Lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta yii, ni awọn banki kan ti n ko owo atijọ naa sẹnu maṣinni wọn, ti awọn araalu si ti n gba a. Ṣugbọn awọn banki kan kọ jalẹ, wọn ko gba owo yii, bẹẹ ni wọn ko ko o jade. Awijare wọn ni pe banki apapọ ilẹ wa ko ti i sọrọ lori boya ki awọn maa gba owo naa abi bẹẹ kọ.

Ṣugbọn pẹlu ọrọ ti Isa sọ yii, ifọkanbalẹ wa fun awọn araalu atawọn banki lati maa gba owo atijọ naa, ki awọn araalu naa si maa gba a.

Nigba ti akọroyin wa ṣabẹwo kaakiri awọn ọja kan niluu Eko, awọn ọlọja kan ṣi n kọ owo atijọ naa, wọn ko gba a lọwọ awọn to fẹẹ fi raja. Awijare wọn ni pe banki apapọ ilẹ wa ko ti i kede pe ki awọn maa gba owo ọhun. Wọn ni bi ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa ṣe paṣẹ lọjọsi pe ka maa nawo naa niyẹn, ti Buhari si pada bọ sita lati sọ pe igba Naira nikan ni kawọn ṣi maa na lọ.

Oṣu Kejila, ọdun to kọja yii, ni banki apapọ ilẹ wa ko owo tuntun, ẹgbẹrun Naira, ẹẹdẹgbẹta ati igba Naira jade lati fi rọpo awọn eyi ti a n na tẹlẹ.

Ọrọ owo naa lo da wahala silẹ tawọn gomina kan fi gba ile-ẹjọ lọ pe ki ile-ẹjọ da banki apapọ ilẹ wa lọwọ kọ lori gbedeke ọjọ ti wọn fi ni kawọn banki fi gba owo naa, ki wọn si fi kun ọjọ ti owo atijọ naa yoo fi wa nita.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu yii, ni ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa paṣẹ pe ki owo atijọ naa maa jẹ nina titi ipari ọdun yii ti wọn yoo ko o kuro nilẹ patapata.

Leave a Reply