Bashiru fẹẹ fi sisọọsi tu ifun dokita to gbẹbi iyawo ẹ n’Ilọrin

Stephen Ajagbe,Ilrin

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nile-ẹjọ ibilẹ kan to wa niluu Ilọrin gbe baale ile kan, Baṣhiru Abdullahi, sahaamọ ọgba ẹwọn. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o dunkooko mọ ẹmi, Ibrahim Adedo, dokita to n tọju iyawo rẹ.

Bashiru ni wọn lo yọ sisọọsi si dokita naa ninu ọfiisi rẹ, to si n halẹ lati fi gun un pa, nitori ẹgbẹrun marundinlọgọrin naira, #75,000, ti wọn ni ko san fun iṣẹ-abẹ iyawo rẹ.

Agbẹjọro ijọba, Nyang Ndifilike, ṣalaye fun ile-ẹjọ pe lẹyin ti olujẹjọ naa muti yo tan, o gba ọọfiisi dokita naa lọ lati lọọ halẹ mọ ọn.

Nyang ni ẹgbẹrun lọna ogun naira ni Bashiru ri san ninu owo ti wọn ni ko lọọ wa lati fi gbẹbi iyawo rẹ nipa iṣẹ-abẹ. Ṣugbọn ọkunrin naa ni wọn gbọdọ yọnda iyawo oun lai ti i sanwo tan.

O ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ẹsun ti wọn fi kan an. O rọ ile-ẹjọ lati gbe e sahaamọ titi ti iwadii to n lọ yoo fi dopin.

Adajọ Abdulrasak Abdulganiyu kọ lati gba oniduuro olujẹjọ naa. O ni ko ṣi wa ni ọgba ẹwọn to wa ni Mandala titi di ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

Leave a Reply