‘Bẹẹ ba tun ri mi nidii ole jija, ohun to ba wu yin ni kẹ ẹ fi mi ṣe’

Adewale Adeoye
Pẹlu gbogbo ẹbẹ ti ole kan bẹ pe kawọn araalu ti wọn mu un dariji oun, sibẹ, wọn ko gba ẹbẹ rẹ, ṣe ni wọn dana sun un, to si jona deeru gburu-gburu ko too di pe awọn ọlọpaa ti wọn fẹẹ waa doola ẹmi rẹ de sibi iṣẹlẹ naa.
ALAROYE gbọ pe pẹlu ibinu nla ni awọn eeyan agbegbe Green Villa, ni Biogbolo, nijọba ibilẹ Yenagoa, fi dana sun ọmọkunrin kan tọwọ wọn tẹ pe ṣe lo maa n ja awọn araalu ọhun lole dukia wọn bii foonu ati goolu ni gbogbo igba.
A gbọ pe nibi ti ole naa ti wọn sọ pe ko le ju ọmọ ọgbọn ọdun lọ ti n ja ọgbẹni kan lole foonu igbalode rẹ lawọn araalu naa ti ri i, ti wọn si sare ṣa ara wọn jọ lati koju rẹ. Oniruuru awọn ohun ija oloro bii: ada, igo, apola-igi ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn fi n le ole naa ko too di pe ọwọ wọn tẹ ẹ, ti wọn si lu u bajẹ, ko too di pe wọn tun dana sun un deeru.
A tiẹ gbọ pe kọwo too tẹ ẹ ni ole naa ti kọkọ lọọ jale lagbegbe naa, to si yinbọn ọwọ rẹ soke tako-tako lati fi dẹru ba awọn eeyan, ko le raaye sa lọ.
Ṣugbọn iku ti yoo pa a lo tun ni ko waa jale lagbegbe naa tọwọ awọn to ti n ṣọ ọ tẹlẹ fi tẹ ẹ, ti wọn si da sẹria iku fun un loju-ẹsẹ.
Ẹnikan to gba lati ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe awọn ọdẹ agbegbe naa ti kọkọ mu ole yii ninu oṣu Kẹta, ọdun yii, ti wọn si fa a le awọn ọlọpaa kan lọwo pe ki wọn lọọ ba a ṣẹjọ, ṣugbọn tawọn ọlọpaa ọhun ju u silẹ.
Ibinu pe tawọn ọlopaa ba tun gba a silẹ, o ṣee ṣe ki wọn tun da a si ni awọn eeyan yii ṣe kuku ṣedajọ ẹsẹkẹsẹ fun un ni gbara, tọwọ wọn tẹ ẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, S.P Asinim Butswat, ni loootọ lawọn gbọ si iṣẹlẹ naa, ati pe kawọn ọlopaa too de lati doola ẹmi arakunrin ti wọn fẹsun ole kan yii ni awọn araalu to mu un ti dana sun un deeru patapata.
Asinim ni ki i ṣohun to daa rara bawọn araalu naa ṣe ṣedajọ oju-ẹsẹ fun afunrasi naa, o ni ohun ti ofin sọ ni pe ki wọn fa ẹni ti wọn ba mu le ọlọpaa lọwọ ni.

Leave a Reply