Bi ejo ba bu eeyan jẹ ni Kwara, ọfẹ ni wọn yoo tọju ẹ

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, ti paṣẹ fun gbogbo ileewosan ijọba, to fi mọ ileewosan ẹkọṣẹ fasiti Ilọrin, UITH, lati maa tọju ẹni ti ejo ba bu ṣan lọfẹẹ.

Kọmiṣanna feto ilera ni Kwara, Dokita Razak Raji, lọ sọrọ ọhun lỌjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii nigba ti ajọ kan, Sir Emeka Offor Foundation, pẹlu ibaṣepọ Savannah Centre for Development, Diplomacy and Democracy, gbe ẹbun awọn ibusun ọgọrun-un kan, awọn oogun oyinbo pẹlu awọn nnkan mi-in fun ileewosan UITH naa.

Dokita Raji ṣalaye pe Gomina Abdulrahman ti pin awọn abẹrẹ to n pa oro ejo sawọn ileewosan kaakiri lati jẹ ki wọn maa lo o fun araalu lai gba kọbọ lọwọ wọn.

O ni yala nileewosan ẹkọṣẹ tabi gbogbogboo to wa ni ipinlẹ Kwara lawọn aporo ejo naa ti de, awọn ileewosan paapaa ti jẹrii si i pe kinni ọhun ti tẹ wọn lọwọ.

O gboriyin fun ajọ to ko ohun iranwọ fun UITH pẹlu bo ṣe rọ awọn ti Ọlọrun ṣẹgi ọla fun lawujọ atawọn lajọlajọ lati gbe iru igbesẹ bẹẹ.

 

One thought on “Bi ejo ba bu eeyan jẹ ni Kwara, ọfẹ ni wọn yoo tọju ẹ

Leave a Reply