Ki i ṣe awọn ọmọge nikan ni wọn gbọdọ maa ṣọra lati wọ aṣọ ti yoo fi ara wọn silẹ tabi rin irin to le mu ki ọkunrin ṣẹwọ si wọn o, awọn agbalagba obinrin naa gbọdọ maa ṣọra wọn gidi pẹlu aṣọ ti wọn yoo wọ ati bi wọn yoo ṣe rin ni titi bi wọn ba n lọ. Sani Garba lo fi eleyii han ni Suleja. Ọmọ ọdun mejilelọgbọn ni Sani, ṣugbọn iya oniyaa kan to jẹ ọmọ ọgọta ọdun geere lo lọọ ka mọle ẹ to si fipa ba a lo pọ, to gbo iya naa mọlẹ karakara.
Igba ti ọwọ awọn ọlọpaa Suleja tẹ Sani lori ọrọ yii, ti wọn waa n beere pe ki lo ro debẹ, ki lo ri lọbẹ to fi waro ọwọ, ọmọọkunrin naa dahun pe o ti pẹ ti oun ti maa n wo iya naa bo ba n rin lọ, ati pe bo ṣe maa n judi ẹ to ba n rin yii lo jẹ ko ti wa lọkan oun pe oun yoo ṣe nnkan pẹlu iya yii ni tipatipa. O ni yatọ si pe oun fẹran lati maa ṣe nnkan pẹlu awọn agbalagba obinrin, idi ti iya yii n ju lo fa ọkan oun sọdọ ẹ.
Wọn beere idi ti Sani fi n fi ipa ba obinrin sun, o si ṣalaye pe ko si idi kan ti oun fi n ba wọn sun ju pe oun ko lowo ti oun yoo fi fẹyawo, tabi ti oun yoo fi ni ọrebinrin ti awọn le jọ maa ṣe, eyi lo fa a to jẹ bi oun ba ti ri obinrin to wu oun, paapaa awọn agbalagba, oun a lọọ ka wọn mọle lati fipa ba wọn ṣe. Ọga ọlọpaa Suleja to fi ọdaran naa han, Wasiu Abiọdun, ti sọ pe wọn n wọ Sani lọ sile ẹjọ niyẹn o, nibẹ ni yoo ti ṣalaye fadajọ ohun to pa a pọ pẹlu awọn agbalagba obinrin.