Ọlawale Ajao, Ibadan
Ile-ẹkọ giga fasiti ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣẹṣẹ da silẹ yoo mu igbelarugẹ ba eto ọrọ aje ipinlẹ naa.
Abẹnugan ileegbimọ awọn aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Debọ Ogundoyin, lo fi igbagbọ rẹ yii han ni kete ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, fọwọ si ofin to yiyi ile-ẹkọ olukọni ijọba ipinlẹ Ọyọ pada si yunifasiti lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Ni bayii, Emmanuel Alayande College of Education, to wa niluu Ọyọ, ti di Emmanuel Alayande University of Education.
Ọnarebu Ogundoyin woye pe bi yunifasiti yii ba ṣe n gba ẹgbaagbeje awọn ọdọ to n lakaka lati wọ ileewe giga wọle leto ọrọ aje ipinlẹ Ọyọ yoo maa gbooro si i.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “A tun ti fi itan mi-in balẹ nipinlẹ Ọyọ lonii. Aṣeyọri ti ko lẹgbẹ gbaa leyi jẹ ninu itan ipinlẹ yii. Ofin tí Gomina Makinde fọwọ si yii ti ṣafihan wọn gẹgẹ bii olufẹ eto ẹkọ ati idagbasoke ilu.
“Awa gẹgẹ bii aṣofin, a ti ṣe ojuṣe tiwa pẹlu sisọ aba ayipada ileewe yii dofin lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii”.
Pẹlu ayipada Emmanuel Alayande College of Education si Emmanuel Alayande University of Education yii, ile-ẹkọ fasiti to jẹ ti jọba ipinlẹ Ọyọ ti di mẹta ọtọọtọ bayii.
Ta o ba gbagbe, ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2021, ni Ladoke Akintola University of Technology (LAUTECH), eyi ti ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun jumọ ni tẹlẹ, di tipinlẹ Ọyọ nikan, lẹyin asọyepọ ọrọ ati adehun to waye laarin awọn ipinlẹ mejeeji.
Ṣaaju, iyẹn lọdun 2017, nijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ iṣakoso Oloogbe Abiọla Ajimọbi, da yunifasiti imọ ẹrọ ta a mọ si Technical University silẹ, tileewe ọhun, eyi to jẹ ile-ẹkọ fasiti imọ ẹrọ akọkọ to jẹ ti jọba ipinlẹ lorileede yii, si bẹrẹ eto ẹkọ lọdun 2018.