Bi ọlọpaa tabi ṣọja ba fiya jẹ Yoruba kan lọna aitọ, a maa sọ ọ dogun mọ wọn lọwọ ni- Sunday Igboho

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Ajijagbara fun ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni ti gbogbo aye mọ si Sunday Igboho ti yari kanlẹ, o ni bi awọn eeyan, paapaa ju lọ, ẹya Fulani ṣe maa n fiwọsi lọ iran Yoruba ti to gẹẹ, ati pe lati asiko yii lọ, bi ẹnikẹni ba tun fiya jẹ ọmọ Yoruba, ogun gidi loluwa rẹ n fa lẹsẹ nitori oun ko ni i gba fun ẹnikẹni lati fọwọ ọla gba ọmọ Yoruba kankan loju mọ.

Nibi ipade oniroyin agbaye ti awọn adari ẹgbẹ Nationalities Alliance for Self-Determination (NINAS), iyẹn ẹgbẹ to n ja fun ominira ẹya wọn lati yapa kuro lara Naijiria, ki wọn le da duro gẹgẹ bii orileede tiwọn laaye ọtọ, ṣe n’Ibadan lo ti sọrọ naa nirọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ana.

Ṣaaju ni Ọjọgbọn Banji Akintoye ti sọ pe gbogbo eto lo ti pari lati fa ẹya Yoruba yọ kuro lara orileede Naijiria, ka si da duro gẹgẹ bii orileede kan ti yoo maa jẹ Ilẹ Olominira Oodua, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni Oodua Republic.

Nigba to n jẹjẹẹ atilẹyin rẹ fun ominira Yoruba, Igboho Ooṣa sọ pé “Baba to n lepa atubọtan rere l’Ọjọgbọn Banji Akintoye. Wọn wo o pe ki

lawọn fẹẹ fi silẹ nigba ti awọn ba dagba, ki ni abọ ti awọn fẹẹ jẹ fun awọn ti to ti rebi agba a re nigba ti awọn naa ba papoda. Iyẹn ni wọn ṣe n lakaka lati mu awa Yoruba de ilẹ ileri.

Wọn tiẹ ti gbe wa de ilẹ ileri gan-an ni, nitori a ko ni i boju wẹyin mọ lori ipinnu wa lati gba ominira fun ilẹ Yoruba.

“Ẹru kankan o ba wa nitori Ọlọrun lo gbe baba wa dide, o si fi awa akinkanju ọmọ ta wọn lọrẹ.

“A wa ni Naijiria, a ko ni ifọkanbalẹ. Awọn Fulani n ba awọn obinrin wa sun, wọn n ṣe fidio rẹ ranṣẹ si gbogbo aye. Wọn n yan wa jẹ, wọn tun n fi i han wa. Iru orileede wo la wa yii gan-an na?

“Gbogbo ipo agbara to n bẹ ni Najiria nibi, ko si Yoruba nibẹ. Yoruba ki i jẹ olori ologun, Yoruba ki i jẹ olori aṣọbode. Eti omi wa mejeeji ta a ni nilẹ Yoruba, gbogbo awọn to n ṣolori nibẹ, Fulani ni wọn, a o fẹ wọn mọ.

Lẹyin ta a ba ti pari ipade yii, awa Yoruba kan maa lọọ ṣepade, a maa ṣi gbogbo bode wa ti ijọba Naijiria ti ti pa silẹ ki irẹsi atawọn ọja ta a maa n ko wọle le maa raaye wọle daadaa.

“Ominira fun Yoruba la fẹ. O si ti bẹrẹ lati oni ti mo n sọrọ yii. Ta a ba gbọ pe ọlọpaa tabi soja fọwọ kan ọmọ Yoruba kan lọna iyanjẹ, yoo dogun ni o. O ti to gẹẹ.

“Mo n gba ẹnu gbogbo ọmọ Yoruba sọrọ pe a ko fẹ awọn Fulani ajinigbe, awọn Fulani apaayan lori ilẹ baba wa mọ. Lati ọla lọ Ọjọbọ, Tọsidee, a oo bẹrẹ si i lọọ ba awọn baba wa ti wọn jẹ agbẹ sọrọ pe ki wọn pada soko. A o si ri i pe a mojuto wọn, ti awọn Fulani ko fi ni i le maa ba nnkan oko wọn jẹ mọ. Awọn Fulani yii n ba nnkan oko wa jẹ ki awọn le maa ribi ko awọn nnkan oko tiwọn waa ta fun wa nibi ni.

“Iru awọn aye ijẹkujẹ ti wọn n jẹ yii naa lo jẹ ki aafin Seriki lasan lasan nilẹ Yoruba daa ju aafin awọn odidi ọba mi-in nilẹ baba wa lọ. A dupẹ pe baba wa Olubadan ti ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe, wọn ti fi Seriki kan n’Ibadan sipo rẹ, wọn ni abẹ Baalẹ agbegbe rẹ lo wa.

“Gbogbo iya ti awọn Fulani fi n jẹ wa nilẹ wa, wọn o bi ọmọ Yoruba kan daa ko ṣe bẹẹ nilẹ Hausa. Ki lo de ti wọn waa sọ wa dẹru nilẹ baba wa. A n sun ninu ile wa, ọkan wa ko balẹ, a n rin laarin ilu, ọkan wa o balẹ. Ki lo de? Ṣẹru ni wa ni?! A ko ṣi aye wa, olori la ṣi yan. A si la o ṣe mọ.

“Ọba to ba sọ pe oun ko si lẹyin wa (lori ominira Yoruba), ko lọọ ṣe fidio ka ri i.

Imọran mi fun ẹyin ọmọ Yoruba to wa nilẹ Hausa ni pe kẹ ẹ maa bọ nile. Iya to n jẹ wa yii ti to o. Gbogbo ọmọ Yoruba, ẹ ma jẹ ka bara wa ja. Ẹ jẹ ka ṣe ara wa lọkan. Asiko ti to, ile ti ya o.”

 

Leave a Reply