Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Alaga igbimọ ti ẹgbẹ oṣelu PDP gbe kalẹ lati ṣe ifilọlẹ ijọba tuntun nipinlẹ Ọṣun, Rẹfurẹndi Bunmi Jenyo, ti sọ pe ko si ṣiṣe, ko si aiṣe fun ẹgbẹ oṣelu APC ju ki wọn gbejọba fun Sẹnetọ Ademọla Adeleke lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Jẹnyọ ṣalaye pe ọro ofin orileede Naijiria ni, bo ti wu ki ẹgbẹ APC maa fẹsẹ janlẹ to, Gomina Adegboyega Oyetọla gbọdọ gbejọba fun gomina tuntun tawọn araalu dibo yan lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, nitori ko si nnkan ti wọn ri ṣe si i.
Nigba to n dahun ibeere awọn oniroyin lẹyin ti wọn ṣe ifilọlẹ igbimọ ti yoo ṣe kokaari eto ifilọle ijọba tuntun naa ni sẹkiteriati ẹgbẹ wọn niluu Oṣogbo, ni Jẹnyọ sọ siwaju pe “A maa ri i daju pe gbogbo eto lo lọ nirọwọrọsẹ, inu gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ni yoo si dun si ayẹyẹ naa.”
Bakan naa ni adele alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun, Dokita Akindele Adekunle, sọ pe bi ẹgbẹ oṣelu APC ko ṣe fọwọsowọpọ pẹlu awọn lori bi wọn yoo ṣe gbejọba silẹ loṣu to n bọ ko tu irun kankan lara awọn rara.
O ni ẹgbẹ PDP ti ṣe gbogbo eto to yẹ lati ri i pe eto gbigba ijọba lọwọ ẹgbẹ APC lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, kẹsẹjari.
Adekunle ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu APC ati Gomina Adegboyega Oyetọla ko nawọ ifẹ si gomina tuntun, Ademọla Adeleke, rara, bẹẹ ni ko si asọpọ ọrọ lori bi wọn yoo ṣe gbejọba silẹ.
O ni, “Iyalẹnu lo jẹ pe titi di asiko yii, ẹgbẹ to n ṣakoso lọwọ ko ti i pe ipade kankan pẹlu ẹgbẹ wa lori bi igbejọba silẹ loṣu to n bọ yoo ti ri, bẹẹ naa si ni Gomina Oyetọla ko ti i ki Adeleke ku oriire, ṣugbọn gbogbo eleyii ko mi wa lọkan rara.
Adekunle rọ awọn ọmọ igbimọ naa lati ṣiṣẹ takuntakun ni oniruuru ẹka ti wọn wa, ki wọn si ri i pe wọn ni akọsilẹ aṣeyọri ti ko lẹgbẹ lori ojuṣe ti wọn gbe le wọn lọwọ lẹlẹkajẹka.