Bibeli ni Godwin lọọ ji nileetaja tọwọ fi tẹ ẹ

Faith Adebọla

Ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji kan, Godwin Idumu, ti n kawọ pọnyin rọjọ nile-ẹjọ Majisreeti to wa n’Ikẹja, ipinlẹ Eko, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o jale, ẹẹmeji ọtọọtọ ni wọn lo ji Bibeli nileetaja igbalode Ebeano supamakẹẹti.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii,  ni wọn wọ afurasi to n gbe Ojule Kẹsan-an, Opopona Emmanuel, lagbegbe Maryland, l’Ekoo, ti igbẹjọ si bẹrẹ lori ẹsun naa.

Ninu alaye ti agbefọba ṣe lati fidi ẹsun rẹ mulẹ, Inpẹkitọ Felicia Okwori ni kamẹra to n ṣofofo awọn alafọwọra bii ti Godwin yii wa ninu ileetaja ọhun, amọ ibi kọlọfin kan tawọn eeyan o le tete fura si ni wọn fi i si, kamẹra ọhun lo si jẹ ki wọn mọ pe ẹni yii lo ji Bibeli ti wọn ti n wa ọhun, wọn lo kọkọ ji Bibeli meji ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun mọkanlelaaadọta ati ọgọrin Naira lọjọ kẹrin oṣu kejila ọdun to kọja.

Lọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ni wọn lo tun pada sileetaja kan naa, ko si ji nnkan mi-in ju Bibeli lọ, Bibeli kan ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun mọkanlelogun ati aadọjọ Naira lo ji.

Wọn lẹṣẹ to da naa ni ijiya to gbọpọn labẹ isọri ọrinlerugba ati meje iwe ofin ilẹ wa, bẹẹ ni ko ba ohun to wa ni isọri irinwo le mẹrinla iwe ofin iwa ọdaran ilu Eko mu.

Afurasi naa loun ko jẹbi ẹsun yii, eyi lo mu ki Onidaajọ H. B. Mọgaji paṣẹ ki wọn da afurasi naa pada sahaamọ titi di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ti igbẹjọ maa tẹsiwaju.

Amọ, o faaye beeli silẹ, o lo gbọdọ ni ẹgbẹrun lọna igba Naira, oniduuro ẹ naa si gbọdọ ni iye owo yii pẹlu.

 

Leave a Reply