Faith Adebọla
“Ni yajoyajo, lai tun fakoko ṣofo mọ, Naijiria gbọdọ gbe awọn igbesẹ ti mo fẹẹ mẹnuba yii, ta a ba fẹ ki nnkan daa:
“A gbọdọ kọkọ bẹrẹ atunto lori eto oṣelu wa, ka pe apero apapọ lori ẹ ko too pẹ ju. Bi ariwo aifararọ ati ijangbara ṣe n roke lala kaakiri agbegbe orileede yii, ami lo jẹ pe aleebu gidi ti wa ninu okun ajọṣe to so wa pọ, o si yẹ ka jokoo yi tabili po, ka jọ sọ ọ nitubi-inubi, ka fẹnu ko lori ohun ti gbogbo ẹlẹkajẹka orileede ba fẹ, iru Naijiria ti wọn lalaa ẹ, ki wọn sọ ọ.”
Alaga ẹgbẹ awọn gomina lorileede yii, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, to tun jẹ gomina ipinlẹ Ekiti lọwọlọwọ, lo la ọrọ yii mọlẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, niluu Eko.
Fayẹmi ni Olubanisọrọ pataki nibi ayẹyẹ Aṣọye Akanṣe ti ọgọta ọdun ti ile-ẹkọ (Nigerian Institute of International Affairs) ti wọn ṣe ni Victoria Island, l’Ekoo.
Gomina naa tẹsiwaju pe: “Ṣiṣe atunto lori ajọṣe wa ni Naijiria maa tubọ fẹsẹ orileede yii mulẹ lọna ati goke agba ni, yoo si ṣalekun iṣọkan ati ojuṣe ta a gbọdọ ṣe ka le jẹ adun awọn nnkan meremere ti ilẹ wa ni, atunto ki i ṣe nnkan to yẹ ka sa fun.”
O sọ pe lara anfaani atunto ni pe agbara oṣelu ati iṣakoso to wa lọwọ ijọba apapọ yoo dinku, awọn ijọba ibilẹ ati ipinlẹ yoo le maa ṣepinnu lori awọn araalu niwọn bo ti jẹ pe awọn ni wọn sun mọ wọn ju lọ, ipindọgba yoo si wa lori ba a ṣe n pin awọn nnkan alumọọni ati owo-ori tijọba n pa.
O ni bii ẹni to fina sori orule sun ni ta a ba ṣi n foni-donii fọla-dọla lori eto atunto orileede yii.