Kazeem Aderohunmu
Sẹnetọ Babafẹmi Ojudu, ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ekiti, sọrọ kan laipẹ yii, ohun to si sọ ni pe, ti Bọla Tinubu ba fẹẹ dije dupo Aarẹ orilẹ-ede yii, ki i ṣe iru Dokita Kayọde Fayemi, gomina ipinlẹ Ekiti ni yoo sọ pe o ku ibi ti yoo gba.
Ọkunrin oloṣelu yii sọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori ohun to n da wahala silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC l’Ekiti, paapaa lori bi igbimọ kan ti wọn fara mọ Gomina Fayẹmi ninu ẹgbẹ oṣelu naa ṣe lawọn ti yọ oun atawọn eeyan ẹ ninu ẹgbẹ. Bẹẹ lawọn naa si tun kede pe, nipinlẹ Ekiti, Kayode Fayẹmi naa ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC mọ, ko lọọ jokoo sile.
Bọrọ ọhun ṣe wa niyẹn ki igbimọ apaṣẹ egbẹ naa loke too sọ pe, ki awọn ikọ mejeeji yii sinmi ogun, ko sẹni to gbọdọ yọ ẹnikenikẹni ninu ẹgbẹ.
Ojudu ni Fayẹmi ti sọ ara ẹ di ooṣa akunlẹbọ l’Ekiti, ati pe awọn to jẹ ọta ẹgbẹ naa gan-an ni gomina ọhun n ba ṣe.
O ni o lawọn eeyan kan to n ṣiṣẹ fun lati doju ẹgbẹ naa bolẹ pẹlu erongba pe ko ni i si ohun to n jẹ ẹgbẹ APC mọ lẹyin ti Buhari ba pari ijọba ẹ lọdun 2023.
Ṣiwaju si i, Ojudu ni Bọla Tinubu to ija ara ẹ gbe daadaa, ati pe to ba wu u lati di aarẹ Naijiria, ko si ọna kan bayii ti Fayẹmi le gba lati fi di i lọwọ. O ni dipo bẹẹ, niṣe lo yẹ ko kọkọ gbe patako ipolongo ibo fun Tinubu, ti tọhun ba sọ pe ipo aarẹ Naijiria wu oun, nitori pe Aṣiwaju Bọla Tinubu gan-an lo ran Fayẹmi lọwọ to fi ri ipo gomina pada si l’Ekiti.
Ojudu sọ pe lara ohun to n da wahala silẹ ninu ẹgbẹ ọhun l’Ekiti ko ju iwa ti Gomina Kayọde Fayẹmi n hu ninu ẹgbẹ. O ni, “Ọpọ igba la ti pariwo fun gomina yii titi pe ko jokoo sile, ko mojuto iṣẹ idagbasoke ilu, ko yee fo kiri bii ẹyẹ, ko si lo awọn ohun ta a ni daadaa lati fi mu iṣẹ idagbasoke ba ipinlẹ wa.
“Bakan naa lo tun ti sọ ẹgbẹ oṣelu APC di dukia ẹ, to n ṣe e bo ṣe wu u, bẹẹ ajọni lọrọ ẹgbẹ, ki i ṣe dukia gomina kankan. Nitori ti Fayẹmi jẹ alaga fun gbogbo awọn gomina, eyi lo mu un maa ri ara ẹ gẹgẹ bii igbakeji aarẹ ni Naijiria, ti ki i bọwọ fẹnikẹni. Ko ṣee ba sọrọ, ẹ ko le ri i, bẹẹ ni ko bọwọ fun awọn ọba alaye wa paapaa, bẹẹ ni ko yẹ ki eeyan sọ ara ẹ di ọlọrun kekere nitori to wa nipo kan.”
Ojudu ti sọ pe ohun to jẹ oun logun gẹge bii oloṣelu ni lati ri Ekiti gẹgẹ bii ipinlẹ to ni ilọsiwaju, ti awọn eeyan yoo maa gbe igbe aye gidi, ti ootọ yoo jọba ninu iṣẹ ilu, tawọn eeyan yoo si bọ lọwọ oṣi ati iya. O ni ohun to ṣee ṣe ni, nitori gbogbo nnkan to le tete mu ipinlẹ dagbasoke nipinlẹ Ekiti ni daadaa.