Bijọba ko ba fopin si bi wọn ṣe n pa awọn eeyan wa, a ko ni i ta maaluu ati ohun jijẹ mọ-Tahir

Ẹgbẹ kan to ni i ṣe pẹlu awọn Fulani darandaran atawọn to n ta ohun jijẹ ti fun ijọba apapọ lọjọ meje lati fopin si bi awọn eeyan ṣe n pa awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun kaakiri awọn ipinlẹ kan ni Naijiria.

Ẹgbẹ yii sọ pe ṣaaju asiko yii loun ti ke si ijọba apapọ, ile-igbimọ aṣofin agba, awọn olori ẹṣọ alaabo, ṣugbọn ti oun ko ri abajade esi kankan.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni Aarẹ ẹgbẹ naa, Muhammad Tahir, sọrọ yii fawọn oniroyin niluu Abuja.

Awọn Fulani darandaran yii ti waa sọ pe ti ijọba atawọn ti oun ti fẹjọ sun tẹlẹ ko ba wa nnkan ṣe lori bi wọn ṣe n pa awọn eeyan awọn lawọn ibi kan ni Naijiria, awọn ṣetan lati daṣẹ silẹ, ti awọn eeyan ko ni i ri maaluu jẹ mọ.

Tahir ni awọn ọmọ ẹgbẹ awọn ti wọn n ta maaluu atawọn ti wọn n ta ohun jijẹ ni ọpọ iya n jẹ lorilẹ-ede yii pẹlu bi awọn eeyan ṣe n kọ lu wọn, ti ijọba ko si rohun kankan ṣe si i.

O fi kun un pe lasiko wahala EndSars to kọja, ọmọ ẹgbẹ awọn bii mọkanlelaaadọjọ (151) ni wọn pa, ti eeyan to tun le ni ọgọrun-un tun ṣofo ẹmi lasiko wahala to ṣẹlẹ ninu ọja Ṣaṣa, niluu Ibadan, ni nnkan bii ọsẹ meji ṣeyin.

Ọkunrin yii sọ pe awọn ti kọ lẹta si Aarẹ Muhammadu Buhari,  lori bi wọn ṣe n pa awọn eeyan oun yii, ṣugbọn ti esi kankan ko ti i wa latọdọ Aarẹ.

Ni bayii, biliọnu aadọta-lenirinwọ (N450bn) ni ẹgbẹ yii loun fẹẹ gba lọwọ ijọba lati fi mojuto gbese nla ti awọn ọmọ ẹgbẹ oun jẹ latara ikọlu oriṣiiriṣii to ṣẹlẹ si wọn.

Bakan naa ni wọn tun rọ ijọba apapọ ko ṣẹto bi iwe adehun yoo ṣe wa laarin ẹgbẹ naa atawọn ijọba ipinlẹ pe ti wọn ba tun kọ lu ọmọ ẹgbẹ naa nibikibi, niṣe lawọn yoo ko gbogbo ohun ti awọn n ta kuro nilẹ, tawọn eeyan ko ni i lanfaani lati ri wọn ra mọ.

O ni o ṣe pataki ki ijọba Buhari tete gbe igbesẹ lori ohun tawọn beere fun, bii bẹẹ kọ, gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa jake-jado Naijiria ni yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi.

Leave a Reply