Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọpọlọpọ awọn alatilẹyin Ọnarebu Bashiru Ọmọlaja Bọlarinwa tawọn eeyan mọ si BOB lo fi idunnu wọn han pẹlu ijo, ilu ati orin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, lẹyin ti igbimọ alakooso apapọ ẹgbẹ APC l’Abuja ṣebura fun ọkunrin naa lati tẹsiwaju gẹgẹ bii Alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Kwara titi di ọdun 2021 ti eto idibo awọn oloye ẹgbẹ tuntun yoo waye.
Ṣaaju ni igun kan lẹgbẹẹ APC, eyi ti Akọgun Iyiọla Oyedepo jẹ agbẹnusọ fun ti naka abuku si Gomina Abdulrazaq Abdulrahman pe o n wa gbogbo ọna lati gbegi dina Bọlarinwa nitori ija abẹle to ti wa laarin wọn fun igba diẹ sẹyin.
Ọjọbọ, Tọside, ti ibura fawọn adari ẹgbẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria yẹ kokọ waye, igbimọ apapọ ẹgbẹ APC ko ranṣẹ pe Bọlarinwa fun ibura naa. Eyi lo mu kawọn to n ṣe atilẹyin fun un gbara ta, wọn fẹsun kan gomina pe o lọwọ ninu ọna lati fi ẹlomi-in to nifẹẹ si rọpo ọkunrin naa.
Ṣugbọn si iyalẹnu awọn ọmọ ẹgbẹ atawọn alatilẹyin BOB, ọjọ Ẹti, Furaidee, ni igbimọ alakooso apapọ ẹgbẹ APC ṣe ibura fun ọkunrin naa ti wọn si ni ko maa ba iṣẹ rẹ lọ gẹgẹ bii Alaga APC ni Kwara.
Awọn alatilẹyin rẹ ninu ẹgbẹ ko le pa idunnu naa mọra pẹlu bi wọn ṣe gba ilu ati ijo, ti wọn si n kọrin pe “BOB, Baba Ramọni”, eyi to tumọ si pe Bọlarinwa ti fi ajulọ han Abdulrahman ti i ṣe gomina.
Lati asiko idibo gbogbogboo to waye lọdun 2019 ni wahala ti bẹ silẹ lẹgbẹ oṣelu APC, paapaa ju lọ laarin Gomina Abdulrahman ati awọn oloye ẹgbẹ APC ti BOB ko sodi. Bawọn kan ṣe n ṣatilẹyin fun gomina bẹẹ lawọn mi-in fi si ọdọ Bọlarinwa.
Ohun ta a hu gbọ pe o n da wahala silẹ ni pe gomina kọ lati ko awọn oloye ẹgbẹ mọra ninu eto iṣejọba rẹ. Wọn l’ọkunrin naa n da gbogbo ẹ ṣe funra rẹ; oun lo yan awọn igbimọ alabaaṣiṣẹ rẹ, bii awọn ipo jakanjankan nile ijọba, kọmiṣanna, oludamọran pataki, oluranlọwọ pataki ati bẹẹ bẹẹ lọ, to si pa gbogbo awọn to ba a ṣiṣẹ to fi de ipo ti.
Bii ina ati omi ti ki i pade ara ni ọrọ Gomina Abdulrahman ati Alaga ẹgbẹ APC, Bọlarinwa, lati ibẹrẹ ijọba yii. Nibi ti ọrọ naa le de oriṣiriiṣii ẹgbẹ lo tun dide ninu APC, ọkan lara ẹgbẹ naa ni ‘AA Group’, iyẹn awọn to n ṣe atilẹyin fun Gomina Abdulrazaq Abdulrahman.
Pẹlu ibi tọrọ gba yọ bayii, awọn amoye ninu ọrọ oṣelu ni kekere ni ija abẹle to n lọ tẹlẹ, eyi to tun n bọ ṣi maa le ju ti atẹyin wa lọ.