Bọọda onikẹkẹ Maruwa n lọ sẹwọn gbere ree o, nigba toun naa fipa ba ọmọ ọdun mẹrinla sun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.

Ile-ẹjọ giga to wa lagbegbe Oke Ẹda ni ilu Akurẹ ti dajọ ẹwon gbere fun onikẹẹkẹ maruwa kan, Blessing Kingsley, nitiori pe o fi tipaitipa ba ọmọbirin ọmọ odun mẹrinla kan lo pọ.

Ọdaran ọhun gbe ọmọdebinrin ta a forukọ bo laṣiiri yii lasiko to n bọ lati ile iyaaya rẹ ni adugbo kan niluu Ondo lọjọ kejila osu keje ọdun 2018 ni.

Dipo ti iba fi gbe e lọ sile ti oun ati iya rẹ n gbe, ile ara rẹ lo fi kẹkẹ Maruwa to n wa gbe e lọ nibi to ti fipa ba a lo pọ, o si tẹ ara rẹ lọrun tan ko too yọnda rẹ ko maa lọ.

Wọn pada fi isẹlẹ yii to awọn ọlọpaa to wa ni tesan Fagun leti, loju ẹsẹ ni wọn si ti gbe igbesẹ ati fi pampẹ ofin gbe e.

Yatọ si ipa to fi ba ọmọ ọlọmọ lo pọ, ayẹwo awọn dokita tun fidi rẹ mulẹ pe o ti ko arun jẹdọjẹdọ ran an nipasẹ ohun to ṣe naa.

Gbogbo eyi ladajo ro pọ lanaa ode yii, ni wọn ba ni ko sọna fọlọtẹ, ki Kingsley maa lọọ fi aṣọ penpe roko ọba titi ti ọlọjọ yoo fi de ba a ni.

 

Leave a Reply