Losiriọsi bọọsi gbina lori ere l’Akoko

Iyiade Oluṣẹyẹ, Akurẹ

Ori lo ko awọn ero inu ọkọ bọọsi lọsiriọsi kan yọ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pẹlu bi ọkọ naa ṣe deedee gbina lojiji lori ere lasiko to n kọja laarin ilu Agbaluku Arigidi Akoko.

Ninu alaye ti ẹnikan to wa nibi iṣẹlẹ ọhun ṣe fun wa, o ni Abuja lọkọ bọọsi elero pupọ naa ti n bọ, to si ti kọja laarin ọpọlọpọ ilu l’Akoko lai si wahala tabi ìyọnu kankan fun un.

O ni loootọ lawọn ero inu ọkọ naa raaye sa asala fun ẹmi ara wọn ti ko si sẹni to ba iṣẹlẹ ijamba ina ọhun rin ṣugbọn ti gbogbo ẹru ati dukia wọn jona gburugburu mọ ọkọ naa.

O ni ṣe lawọn ero atawọn oluworan ti wọn pejọ n wo titi ti ọkọ ati gbogbo ohun ini awọn ero fi jona tan lai si ohunkohun ti ẹnikẹni le ṣe si i.

Oluworan mi-in to porukọ ara rẹ ni Jamiu Alli ni ohun to mu ki adanu awọn ero ọkọ naa pọ to bẹẹ ni ti aisi ileeṣẹ panapana to n ṣiṣẹ ni gbogbo awọn ilu to wa l’Akoko.
Jamiu ni o yẹ kijọba ipinlẹ Ondo tete ṣe atunṣe si ileeṣẹ panapana to wa niluu Ikarẹ, nitori aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan, paapaa lasiko ọgbẹlẹ yii.

Leave a Reply