Boya lọmọ Naijiria yii yoo pada wale mọ, egboogi oloro ni wọn ka mọ ọn lọwọ ni South Africa

Adewale Adeoye

Ninu otẹẹli igbalode kan ti wọn n pe ni Houghton, to wa lagbegbe Johannesburg, lorileede South Africa, lọwọ awọn agbofinro orileede naa to n gbogun ti gbigbe ati lilo egboogi oloro ti tẹ ọmọ ilẹ wa kan to to ẹni ọdun mejidinlaaadọta ti wọn ko fẹẹ darukọ rẹ sita nitori ti iwadii ṣi n lọ lọwọ nipa rẹ. Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni awọn agbofinro orileede naa lọọ fọwọ ofin mu awọn ọdaran ọhun, ti ọkan jẹ ọmọ orileede Naijiria, nigba ti ọrẹ rẹ jẹ ọmọ orileede South Africa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Xolani Fihla, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe awọn araalu kan to mọ nipa iṣẹ ti ko bofin mu tawọn afurasi ọdaran ọhun n se lo waa ta awọn lolobo, tawọn si tete lọọ fọwọ ofin mu wọn ni otẹẹli ọhun. O ni wọn ti wa lahaamọ bayii.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘‘Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni awọn ọlọpaa agbegbe Johannesburg, lorileede South Africa, lọ sinu otẹẹli kan tawọn oniṣẹ ibi naa n lo, wọn lọọ fọwọ ofin mu awọn ọdaran kan ti wọn n ṣokoowo egboogi oloro, obitibiti egboogi oloro la gba lọwọ wọn lasiko ta a lọọ ka wọn mọ otẹẹli ọhun.

Ọmọ orileede Naijiria kan ati ọmọ  South Africa kan la ba nidii iṣẹ to lodi sofin yii, a ti fọwọ ofin mu awọn  mejeeji, wọn si ti jẹwọ pe loootọ awọn lawọn maa n ta egboogi oloro fawọn araalu naa.

Alukoro ni awọn maa too foju awọn ọdaran ọhun bale-ẹjọ laipẹ yii, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn.

Leave a Reply