Buhari ṣi ọna reluwee Eko s’Ibadan

Faith Adebọla
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣi ọna reluwee to lọ lati ilu Ekoo s’ibadan, o ti di lilo faraalu bayii.
Bakan naa lo tun ko awọn ọkọ reluwee tuntun jade bii ọmọ tuntun, lati mu irinajo Eko s’Ibadan rọrun, ko sí tura ju ti atẹyinwa lọ.
Ọjọruu, Tọsidee yii, ni Aarẹ balẹ siluu Eko lati Abuja, bo si ṣe n sọkalẹ ninu ọkọ baaluu to gbe e wa, taara lo wọ ọkọ ayọkẹlẹ lọ si Ebute-mẹta, nibi tí ayẹyẹ ikojade naa ti waye.
Buhari ni aṣeyọri nla ni bi wọn ṣe pari iṣẹ ode yii jẹ fun ijọba oun, o ni inu oun si dun si bawọn araalu ṣe ṣamulo eto irinna tuntun yii, latigba tawọn ti n fi tọ wọn lẹnu wo loṣu mẹfa sẹyin.
Bakan naa ni Buhari sọ pe ọna reluwee igbalode tuntun ọhun ko ni i duro s’Ibadan, eto ti wa lati nasẹ rẹ de ilu Kano, nipinlẹ Kano, bẹẹ lo maa de ilu Maradi, nipinlẹ Niger.
Aarẹ waa gboṣuba fun minisita feto irinna, Rotimi Amaechi, fun isapa rẹ lori iṣẹ yii.
Rotimi Amaechi toun naa wa nikalẹ nibi ayẹyẹ naa sọ pe “Eyi ni iṣẹ eto irinna reluwee ti Aarẹ Buhari ti ko jade bii ọmọ tuntun, iṣakoso Buhari lo bẹrẹ rẹ, to si pari rẹ”, lati fihan pe ọrọ igbaye-gbadun araalu jẹ ìjọba yii logun gidi.
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu naa sọrọ nibi ayẹyẹ ọhun, o ni bijọba apapọ ṣe Jara mọ iṣẹ yii, ti wọn si pari ẹ lasiko, fihan pe Buhari ko koyan ipinlẹ Eko kere rara, o si dupẹ lọwọ Aarẹ fun anfaani yii.
O ni ni bayii, pẹlu ọna reluwee tuntun yii, o ti ṣee ṣe fawọn eeyan lati maa ti ilu Ibadan waa ṣiṣẹ l’Ekoo lojoojumọ, ti wọn ba fẹ bẹẹ.

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: