Faith Adebọla
Olori awọn aṣofin apapọ ilẹ wa ana, Oloye Bukọla Saraki, ti kede pe ọrọ eto aabo to dẹnu kọlẹ lorileede Naijiria lasiko yii, arun oju ni, ki i ṣe arun imu, o ti han gbangba pe apa Aarẹ Muhammmadu Buhari ati ẹgbẹ oṣelu APC (All Progressives Congress) ko kan kinni naa mọ, afi ki wọn tete wa iranlọwọ ki gbogbo nnkan too doju de.
Ori ikanni ayelujara rẹ, tuita, ni Saraki ti sọrọ ọhun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, o ni o ti foju han bayii, ko si ariyanjiyan ninu ẹ mọ pe iṣoro aisi aabo ti mu Buhari ati ẹgbẹ oṣelu APC lomi, ẹru ọhun si ti di atari ajanaku fun wọn.
Bayii lo ṣe kọ ọ sori ikanni abẹyẹfo (twitter) ọhun:
“Lọjọ kan ṣoṣo pere, lati ipinlẹ Anambra si Kaduna, Yobe, Niger ati Eko, awọn iṣẹlẹ buruku nipa iṣoro aisi aabo ṣẹlẹ, wọn ṣẹlẹ gidi ni. Lati wakati kan si ekeji, niṣe ni iroyin ajaabalẹ n waye leralera, a si foju ri awọn iṣẹlẹ iwa ọdaran, ijinigbe, ifẹmiṣofo ati idaluru to lagbara, to si baayan lọkan jẹ kaakiri ọpọ ibi yika orileede yii. Ko yẹ ko ri bayii o.
“A ka nipa bawọn Boko Haram ṣe lọọ ri asia wọn mọ ipinlẹ Niger, nijọba ibilẹ Shiroro, nibi ti ọkan lara ileeṣẹ to n pese ina mọnamọna to pọ ju lọ fun Naijiria wa, bẹẹ ko ju nnkan bii igba kilomita si olu-ilu Naijiria lọ.
“A tun ka nipa ọrọ ti gomina ipinlẹ Niger sọ, to fi n sọ bi awọ ko ṣe kaju ilu fun ijọba lori ọrọ ọhun si, ati bi ẹgbẹẹgbẹrun eeyan ṣe dẹni to sa kuro nibugbe wọn nipinlẹ naa, a tun gbọ bi gomina ṣe sọ pe gbogbo isapa ijọba apapọ ko tu irun kan lara awọn afẹmiṣofo yii.
“A tun gbọ iroyin to gbomi loju eeyan lati ilu Mainok, to wa loju ọna Damaturu si Maiduguri, bawọn agbebọn ṣe ya bo ilu naa lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, ti wọn si n pa awọn eeyan bii ẹni ba adiẹ, ti wọn da ẹmi awọn ṣọja wa ataraalu legbodo lasan. Eeyan mẹsan-an ni wọn lawọn agbebọn tun pa nigba ti wọn ya bo abule Ukpomachi ati Awkuzu, nijọba ibilẹ Oyi, ipinlẹ Anambra.
“Ni Kaduna, awọn janduku tun pa meji mi-in yatọ sawọn mẹta ti wọn ti kọkọ yinbọn pa lara awọn akẹkọọ fasiti ti wọn ji gbe ni Fasiti Greenfield, bẹẹ ni wọn tun ji awọn akẹkọọ Federal University of Agriculture to wa ni Makurdi, ipinlẹ Benue. Laarin ọjọ kan pere in gbogbo eyi ṣẹlẹ. Ko gbọdọ maa lọọ bẹẹ rara.
“O ti foju han rekete pe Aarẹ Buhari ati ẹgbẹ APC nilo iranlọwọ gidi. Ọrọ aabo yii ti pin wọn lẹmi-in, wọn nilo iranlọwọ gbogbo wa.”