Gomina El-Rufai yari: Kọbọ kan o ni i jade lapo ijọba mi sọwọ awọn agbebọn

Faith Adebọla

Bawọn janduku agbebọn to n ṣoro bii agbọn nipinlẹ Kaduna ba lero pe pipa tawọn n pa awọn ọmọleewe ti wọn ji gbe maa mu ki ijọba ipinlẹ naa tete ba wọn wa obitibiti owo ti wọn n beere fun, afaimọ ni ireti wọn ko ni i ja sasan, tori Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai, ti kede pe gbogbo iṣẹlẹ aburu wọnyi ko ni i mu koun yii ipinnu oun pada, o ni kọbọ kan ko ni i jade lati apo ijọba ipinlẹ oun bọ sọdọ awọn agbebọn naa, oun o ni i fowo bẹ wọn bi wọn ṣe ju bẹẹ lọ.

Ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni Muyiwa Adekẹyẹ to jẹ Oludamọran pataki lori eto iroyin ati ibanisọrọ si Gomina El-Rufai fi lede lorukọ gomina ọhun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii lo ti sọrọ naa. Nibẹ ni El-Rufai ti fesi sawọn to n sọrọ si i latari bo ṣe taku pe oun ko ni i fowo bẹbẹ lọdọ awọn agbebọn kankan lati tu awọn ti wọn ji gbe silẹ.

Gomina ọhun ni ki i ṣe igba akọkọ tabi eekeji ree tawọn ijọba ipinlẹ kan ati ijọba apapọ maa fi owo bẹ awọn janduku agbebọn ati awọn afẹmiṣofo lati gba awọn ti wọn mu sahaamọ wọn silẹ, ṣugbọn pẹlu rẹ naa, niṣe lawọn agbebọn ati afẹmiṣofo naa tun maa n tẹsiwaju ninu iwa buruku wọn, ti wọn yoo tun ṣe ohun to buru ju ti tẹlẹ lọ, eyi si fihan pe igbesẹ fifi owo bẹ wọn ko nitumọ, ko si mọgbọn dani niyẹn, oun o ni i ba wọn lọwọ siru nnkan bẹẹ, lai ka bawọn agbebọn naa ṣe n halẹ si.

O ni ojuutu kan ṣoṣo toun mọ to le fopin si iwakiwa tawọn agbebọn ati afẹmiṣofo n hu ni kijọba pa wọn danu, ki wọn gbeja ko wọn gidi, ki wọn si bori wọn patapata.

O ni bii igba teeyan n san ere fun iwa laabi ti wọn n hu lo jẹ lati maa fi owo bẹ awọn agbebọn atawọn ajinigbe, ko si yẹ ki wọn ri ere ninu ọṣẹ buruku ti wọn n ṣe.

Leave a Reply