Aderounmu Kazeem
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ba awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria sọrọ l’owurọ kutu oni, ọjọ kin-in-ni oṣu kín in ni ọdún 2021, nibi to ti ṣèlérí wí pé ijọba oun ṣetan lati ṣamojuto ọpọ nnkan to le mu irọrun ba araalu.
Aago meje owurọ oni lo bọ sórí tẹlifíṣàn NTA, ti awọn ileeṣẹ redio ijọba paapaa gbe e sori afẹfẹ bakan naa. Ninu ọrọ Buhari lo ti sọ nípa ètò aabo, eyi to sọ pe ijọba oun ko ni kaaarẹ ọkan lati mu àyípadà rere bá.
Siwaju sí i, Buhari, sọ pé loootọ loun mọ pe ẹbun nla wa lára ọpọ ọdọ orilẹ ede yii, ati pe ijoba oun ṣetan lati kun wọn lọwọ, ti ala rere wọn yóò ṣẹ lori èròngbà wọn. O ni gbogbo ariwo ati ohun ti wọn n béèrè fún nijọba oun ti gbọ, bẹẹ ni ayipada rere yóò ṣẹlẹ laipẹ jọjọ.
Buhari ni ọdún nla kan ni 2020 to pari yii jẹ fun orilẹ ede Naijiria ati gbogbo agbaye paapaa, ati pe oriire nla ni bi ọdun tuntun tí ṣe wọlé dé wẹ́rẹ́ bayii.
Lafikun, Buhari sọ pé lara awọn aṣeyọri ọdun 2020 ni ayẹyẹ ọgọta ọdún tí Naijiria ṣe, ati pe bi orilẹ ede yii ti ṣe gbé ẹnu le ọdun mọkanlelọgọta bayii, ohun rere ni yóò ṣẹlẹ, ti ijọba òun yóò sì mú lele lori awọn ileri ti oun ti ṣe.
Lori eto aabo, Buhari sọ pe atunto tó yẹ yóò bá a, bẹẹ ni yoo kan awọn oludari ẹ paapaa. O ni koko mẹta yii, eto aabo, idagbasoke ọrọ ajé àti igbogun ti iwa ibajẹ ni koko ohun tí ìjọba òun n ṣiṣẹ gidi le lori, bẹẹ lo ṣèlérí láti ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn aṣofin kí ọrọ Naijiria tubọ le lojutuu ju bayii lọ.
Bakan naa lo sọ pe wahala nla ti àrùn koronafairọọsi ko ba àgbáyé, Naijiria paapaa náà ni ipin níbẹ, bẹẹ lo gba a laduura kí ọlọrun foriji awon ọmọ orílẹ̀-èdè yii to ba iṣẹlẹ ọhun rin.