Buhari fi awọn olori ologun ilẹ wa to yọ nipo ṣe Ambasadọ

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari kede awọn olori ileeṣẹ ologun to yọ nipo laipẹ yii gẹgẹ bii Ambasadọ.

Oludamọran Aarẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina, lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita.

Ninu iwe kan ti wọn kọ si Olori ile-igbimọ aṣofin, Ahmed Lawan, ni Aarẹ ti beere pe ki awọn aṣofin fọwọ si iyansipo awọn eeyan naa.

Awọn olori ologun tọrọ naa kan ni Ajagun-fẹyinti Abayọmi G. Oloniṣakin, Ajagun-fẹyinti Turkur Burantai, Ajagun-fẹyinti Sadique Abubakar ati Ajagun-fẹyinti Muhammed Usman.

Ipo tuntun ti wọn fun wọn yii tumọ si pe wọn le ṣe aṣoju ilẹ wa nibikibi, bo tilẹ jẹ pe wọn ki i ṣe ojulowo akọṣẹmọṣẹ nipa awọn to maa n ṣe aṣoju orileede ti wọn n pe ni (career deplomat) lede oyinbo.

Leave a Reply