Ni bayii, wọn ni opin ti de ba irinajo Ibrahim Magu, ọga agba fun ajọ EFCC, to n jẹjọ lọwọ pẹlu bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe yan ẹlomi-in sipo ẹ.
Ninu ikede ti Oluranlọwọ fun Aarẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Femi Adeṣina, fi sita lo ti sọ ọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti yan Abdul-Rasheed, ẹni ogoji ọdun, sipo alaga ajọ EFCC.
Ninu lẹta ti Buhari kọ si Aarẹ ile-igbimọ aṣofin agba, Ahmad Lawan, lo ti ni ki oun atawọn ọmọ ile-igbimọ asọfin fọwọ si i, ki ọkunrin naa le bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bii ọga agba fun ajọ EFCC.
ALAROYE gbọ pe ẹni ogoji ọdun ni Bawa yii, bẹẹ akọṣẹmọṣẹ ni ti a ba n sọ nipa iṣẹ iwadii ninu ajọ naa. Bakan naa ni wọn sọ pe ọkunrin yii ti ni iriri daadaa lẹnu iṣẹ yii, paapaa lori awọn iwa ọdaran bii awọn onijibiti, ẹsun ikowojẹ ni banki; iwa ajẹbanu, ṣiṣe owo ilu kumọ-kumọ atawọn ẹsun ọdaran mi-in ti ajọ ọhun ti ṣiṣẹ lori wọn daadaa.
Ṣiwaju si i, wọn ni ọpọlọpọ ẹkọ lo ti kọ kaakiri agbaye, bẹẹ lo jẹ ọkan lara awọn ọlọpaa ti wọn fi bẹrẹ ajọ ọhun lọdun 2005.
Ọdọmọkunrin yii kawe jade ni Yunifasiti nibi to ti kawe gboye imọ eto ọrọ aje (Economics), bẹẹ lo gboye aladanla (Masters) ninu imọ to ni i ṣe pẹlu ọrọ to jẹ mọ orilẹ-ede lagbaaye (International Affairs and Diplomacy.”)