Buhari gbe igbimọ ti yoo ṣe amulo ofin tuntun lori ọrọ-epo bẹntiroolu kalẹ

Joke Amọri

Ninu atẹjade kan ti Oludamọran Aarẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, fi sita ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lo ti kede pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti gbe igbimọ kan dide ti yoo ṣiṣẹ lori ofin tuntun ti wọn gbe kalẹ lori ọrọ epo bẹntiroolu atawọn nnkan to jẹ mọ ọn, iyẹn Petroleum Industry Bill, (PIB), eyi  to ni i ṣe pẹlu isakoso ileeṣẹ epo bẹntiroolu nilẹ wa, ofin ti wọn yoo maa lo ati ṣiṣẹ itọju awọn agbegbe ti wọn ti n wa awọn epo naa.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Buhari sọ aba naa dofin. Lara awọn ohun to wa ninu ofin yii ni pe ijọba yoo maa fun awọn agbegbe ti wọn ti n wa epo naa ni ida mẹta ninu ọgọrun-un ohun ti wọn ba ri lori epo bẹntiroolu.

Bakan naa ni ofin yii gba ijọba laaye lati yọ owo iranwọ ti wọn n fi sori epo bẹntiroolu ti wọn n pe (Subusidy) kuro, eyi to fi han pe igbakigba si asiko yii ni owo-epo bẹntiroolu le lọ soke si i.

Lara ohun ti ijọba lawọn tori ẹ fọwọ si ofin yii ni pe yoo jẹ ki awọn olokoowo maa waa dowo-pọ pẹlu ilẹ wa latipasẹ awọn agbegbe ti epo yii wa.

Minisita kekere lori ọrọ epo bẹntiroolu nilẹ wa, to tun jẹ gomina ipinlẹ Bayelsa tẹlẹ, Timipre Sylva, ni yoo jẹ alaga igbimọ ti yoo ri si amulo ofin bẹntiroolu ọhun. Lara awọn ti yoo jọ ṣiṣẹ-pọ pẹlu rẹ laarin oṣu mejila tijọba fun wọn lati ṣiṣẹ lori ọna ti ofin tuntun yii yoo fi rẹsẹ walẹ ni ọga agba patapata fun ileeṣẹ epo bẹntiroolu NNPC, nilẹ wa, ọga ileeṣẹ to n ri si ọrọ owo-ori, FIRS, minisita fun eto idajọ, aṣoju minisita fun eto inawo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣugbọn gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ti sọ pe ida mẹta ninu ọgọrun-un ti ijọba ni awọn yoo fun awọn ipinlẹ ti wọn ti n wa epo, paapaa ju lọ agbegbe Naija Delta, ti kere ju, o ni ko da bii pe ijọba ṣe daadaa si awọn ipinlẹ ti wọn n jiya lori ọrọ owo-epo yii.

Wike ni iṣẹ kekere kọ lo wa nilẹ lati ṣe lori ọrọ awọn ilẹ ti wọn ti n wa epo latọdun yii wa

Ọpọ awọn eeyan ni wọn ti n sọ pe awọn kudiẹ kudiẹ kan wa ninu ofin naa, ti awọn mi-in si tun n pariwo pe awọn apa kan wa ninu ofin naa ti wọn fi ọna eru gbe wọle, ti yoo fun awọn ilẹ Hausa ni anfaani lati maa pin ninu owo-epo yii bo tilẹ jẹ pe ko si epo nilẹ wọn, ti wọn si rọ ijọba lati fun awọn ipinlẹ ti wọn ti n wa epo ni ida marun-un si meje ataabọ, sibẹ Aarẹ Buhari ko beṣu-bẹgba to fi fọwọ si ofin yii ni kete to ti ilu London de.

Leave a Reply