Faith Adebọla
Olori orileede wa, Aarẹ Muhammadu Buhari, ko fakoko sofo rara lati ki Ọjọgbọn Charles Chukwuma Soludo to jawe olubori ninu eto idibo sipo gomina nipinlẹ Anambra kuu oriire, o loun aa ṣiṣẹ pẹlu gomina tuntun ọhun ti wọn ba ti bura fun un, lai fi ti ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ti wọn wa ṣe.
Ninu ọrọ ikini ku oriire kan ti Agbẹnusọ fun Aarẹ, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, buwọ lu l’Ọjọruu, Wẹsidee, gẹrẹ ti wọn kede Soludo bii olubori, ni Buhari ti fi idunnu rẹ han.
Atẹjade naa ka pe “Inu Buhari dun pe lẹyin ọpọlọpọ akitiyan ati ipolongo ibo, Soludo ti ẹgbẹ APGA lo yege, gẹgẹ bi ajọ INEC ṣe kede rẹ.
“Aarẹ Buhari ba Soludo yọ, o si ba ẹgbẹ oṣelu rẹ naa yọ, Aarẹ n foju sọna lati ṣiṣẹ pẹlu gomina tuntun naa laipẹ, ki alaafia, aabo ati idagbasoke le fẹsẹ mulẹ, ki i ṣe ni ipinlẹ Anambra nikan o, ṣugbọn kari gbogbo orileede wa.
Lẹẹkan si i, ẹ kuu oriire o.”
Bẹẹ ni Buhari sọ.