Buhari ko ṣe ohun aburu kankan nigba to fi wa nipo olori Naijiria- Garba Shehu

Adeoye Adewale

‘Ko sohun to jọ pe olori orileede yii tẹlẹ, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, ti sa lọ sẹyin odi, ko sohun to n le e, bẹẹ ni ko hu iwa aidaa lakooko to fi wa nipo olori orileede yii. Ilu rẹ ti i ṣẹ Daura, nipinlẹ Katsina, lo wa bayii, bẹẹ ba fẹẹ ri i, ẹ lọọ ba a nile rẹ. Loootọ lo ti figba kan lọọ fun ara rẹ nisinmi loke okun, nigba tawọn alejo ko yee da wa sile rẹ lo fi lọ siluu oyinbo lati lọọ sinmi, ṣugbọn o ti pada de sorileede yii.’’

Ọgbẹni Garba Shehu to je alakooso eto iroyin ati agbẹnusọ fun Buhari lakooko to fi wa nipo olori orileede yii lo sọrọ naa.

Garba Shehu ni ki i ṣe ohun to daa  bawọn kan ṣe n gbe iroyin ti ko lẹsẹ nilẹ kiri nipa Buhari, ti wọn n sọ awọn ohun ti oju wọn ko to rara.

‘‘Awọn kan n sọ pe Buhari ti sa lọ sẹyin odi kọwọ ma baa tẹ ẹ, ẹni tẹ ẹ n sọ pe o wa lẹyin odi yii, bẹ ẹ ba deluu rẹ, ẹ maa ba nile rẹ to n sinmi, to n jẹ igbadun lọwọ.

‘‘Buhari ko ṣe ohun aburu rara ni gbogbo akoko to fi wa nipo aarẹ orileede yii, ko si idi kan pataki to fi gbọdọ maa sa kaakiri gẹgẹ bi awọn kan ti n sọ.

‘‘Ohun ti ma a rọ awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ naa kiri ni pe ki wọn yẹ ohunkohun ti wọn ba fẹẹ gbe sita wo daadaa ko too di pe wọn gbe irufẹ iroyin bẹẹ jade.

‘‘Loootọ, Buhari lọ siluu oyinbo lati lọọ fun ara rẹ nisinmi diẹ, o si tun lo akooko naa lati ṣepade pataki pẹlu Aarẹ Tinubu, ko si pẹ rara to fi tun pada de siluu yii’’. Garba lo pari ọrọ rẹ bẹẹ.

Leave a Reply