Dada Ajikanje
Aarẹ Muhammadu Buhari, Ahmed Lawan, atawọn oloṣelu mi-in ti ṣapejuwe iku ojiji to pa Ọgbeni Sam Nda-Isaiah gẹgẹ bii adanu nla ni Naijiria.
Aṣaalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ni wọn kede iku Ọgbẹni Sam Nda-Isaiah, ẹni tí i ṣe oludasilẹ iwe iroyin Leadership.
Àìsàn ranpẹ kan ni wọn sọ pe o ṣe ọkunrin ọmọ ipinlẹ Niger ọhun ko too tẹri gbaṣọ lẹni ọdun mejidinlọgọta.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹbi ẹ ko ti i sọ ohunkohun, ALAROYE gbọ pe Tusidee, ọjọ Iṣẹgun, to kọja yii, ni wọn ti ri ọkunrin naa nita gbẹyin, lasiko to kopa nibi ipade awọn oludasilẹ ìwé ìròyìn ní Nàìjíríà, ti oun naa si pẹlu awọn to dibo lati yan awọn oloye tuntun fun ẹgbẹ naa.
Wọn ní bí àìsàn ọhún ti ki i mọlẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ni wọn ti sare gbe e lọ sí ileewosan Nizamiye Hospital, ni Abuja, ṣugbọn nigba ti agbára awọn yẹn kò ka a mọ ni wọn tun gbe e lọ si ileewosan Yunifasiti Abuja, nibi to pada dakẹ si.
A gbọ pe ko si ohun kan bayii to ṣe e nibi ipade ọhun, bẹẹ ni iku ẹ ṣi n jẹ iyalẹnu nla fawọn eeyan nigba ti wọn gbọ pe ọkunrin naa ko si laye mọ.
Yatọ si pe ọkunrin yii jẹ akọṣẹmọṣẹ apoogun, bakan naa lo jẹ oloṣẹlu, ti oun gan-an naa jade lati dije dupo Aarẹ lọdun 2015, labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn ti Aarẹ Muhammadu Buhari fidi ẹ janlẹ ninu idibo abẹle ninu ẹgbẹ oṣelu ọhun.
Ni bayii, Aarẹ Muhammadu Buhari, ti ṣapejuwe iku ọkunrin naa gẹgẹ bi adanu nla, bakan naa lo ba awọn ẹbi ẹ kẹdun gidigidi.
Ni ti Ahmed Lawan, ẹni ti i ṣe olori ile igbimọ aṣofin agba, o ni titi aye lawọn eeyan yoo maa ranti ipa manigbegbe to ko nipa eto idagbasoke lawujọ.