Faith Adebọla
Agbarijọ awọn gomina ti wọn n ṣakoso lọwọ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ti parọwa si olori orileede wa, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, pe ko tete buwọ lu abadofin eto idibo to wa lori tabili rẹ, wọn ni ko daa bi Aarẹ ṣe n fi ibuwọlu naa falẹ lori abadofin ọhun.
Arọwa yii wa ninu atẹjade kan tawọn gomina naa fi lede lẹyin ipade pataki kan ti wọn ṣe l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji yii, niluu Yenagoa, nipinlẹ Bayelsa.
Gomina ipinlẹ Bayelsa, Ọgbẹni Duoye Diri, lo gba awọn ẹlẹgbẹ rẹ lalejo. Gbọngan apero to wa nile ijọba wọn nipade naa ti waye, alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Iyorchia Ayu, naa wa nibẹ.
Atẹjade ti wọn fi lede ọhun ka lapa kan pe: “Awa gomina yii koro oju si iwa aiṣootọ, fifi ẹnu meji sọrọ, abosi ati aṣetunṣe iṣẹ ti ijọba apapọ, eyi ti ẹgbẹ ọsẹlu APC (All Progressives Congress) n dari rẹ yii, n hu lori ọrọ yiyọ afikun owo-ori epo bẹntiroolu kuro, tori wọn ti sọ kinni naa di baṣubaṣu. Iye jala bẹntiroolu ti wọn sọ p’awọn ọmọ Naijiria n lo lojumọ ga kọja afẹnusọ, abumọ ati asọdun gbaa ni. A fẹ ki iwadii to nitumọ waye lori ọrọ yii.
Bakan naa ni inu wa ko dun si bi Aarẹ Buhari ko ṣe ti i fọwọ si abadofin eto idibo tawọn aṣofin apapọ ti ṣatunṣe si, ti wọn si ti fi ṣọwọ si i. A parọwa pe ki Aarẹ tete buwọ lu u, ki ofin naa si tete bẹrẹ iṣẹ, tori ohun ti gbogbo ọmọ Naijiria n reti niyẹn, ki eto idibo to jiire le waye lọdun 2023. A o ri idi ti Aarẹ fi ni lati fakoko ṣofo lẹyin atunṣe tawọn aṣofin ti ṣe yii.
Inu wa dun si aṣẹ tile-ẹjọ pa, bi wọn ṣe da ijọba ipinlẹ Rivers to wọ ijọba apapọ rele ẹjọ lare, ti wọn si da ijọba apapọ lẹbi, pe ko bofin mu, wọn o si lẹtọọ lati maa yọ owo atilẹyin fun ileeṣẹ ọlọpaa ninu akaunti ajumọni ijọba apapọ, eyi tawọn ijọba ipinlẹ n pawo si, ati bile-ẹjọ ṣe ni kijọba apapọ jawọ irufẹ owo yiyọ bẹẹ.
A tun parọwa si ileeṣẹ to n ri si pipin owo fawọn ipinlẹ (RMAFC) lati ṣatunṣe to yẹ si ọna ti wọn fi n pin owo loṣooṣu, ki iye tawọn ipinlẹ yoo maa gba le gbe pẹẹli si i ju tatẹyinwa lọ.”
Lara awọn gomina to pesẹ sipade naa ni Ifeanyi Okowa tipinlẹ Delta, Oluṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ, Samuel Ortom lati Benue, Okezie Ikpeazu lati Abia, Udom Emmanuel lati Akwa Ibom, Bala Muhammed tipinlẹ Bauchi, Ahmadu Fintiri lati Adamawa, Godwin Obaseki lati ipinlẹ Edo, Ifeanyi Ugwuanyi tipinlẹ Enugu, ati Nyesom Wike, tipinlẹ Rivers.