Ọwọ NSCDC tẹ awọn meji pẹlu kẹẹgi epo bẹtiroolu ọgbọn ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, lọwọ ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, tẹ awọn kọlọransi ẹda meji kan,  Yunus Yusuf, ẹni ọdun mejilelọgbọn, ati Ọgbẹni Ismail Olamilekan, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, pẹlu ọkọ akero takisi ni agbegbe Ẹyẹnkọrin, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, pẹlu kẹẹgi epo bẹtiroolu ọgbọn lọwọ wọn.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ naa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, fi lede niluu Ilọrin, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe awọn afurasi ọhun lọọ ra epo naa nipinlẹ to mule ti Kwara, iyẹn nipinlẹ Ọyọ, ti wọn si fẹẹ maa ta a lọwọngogo fawọn olugbe ilu Ilọrin. Afọlabi tẹsiwaju pe ṣaaju ni adari ajọ yii, Ọgbẹni Makinde Iskil Ayinla, ti kilọ pe ẹnikẹni to ba fẹẹ maa fara ni araalu lori ọrọ epo bẹntiroolu nipinlẹ Kwara yoo maa koju ijiya to tọ, ti ajọ naa si n kiri kaakiri awọn ileepo lati fi awọn to ni epo ti ko ta epo fun araalu jofin.

Awọn afurasi naa jẹwọ pe ilu Ogbomọṣọ lawọn ti ra epo ọhun, ti wọn si fẹẹ maa ta a lọwọngogo fun awọn to ba nilo epo ni pajawiri.

Afọlabi ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii lawọn afurasi mejeeji yoo foju ba ile-ẹjọ.

Leave a Reply