Nigbẹyin, ẹgbẹ APC gba lati mu alaga wọn lati ilẹ Hausa

Faith Adebọla

Bi ko ba tun si ayipada ojiji mi-in, o jọ pe agbegbe Aarin-Gbungbun Ariwa ni ẹni ti yoo bọ si ipo alaga apapọ fun ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) yoo ti wa.

Ọrọ yii wa lara ohun tawọn gomina atawọn agbaagba ẹgbẹ APC fẹnu ko le lori nibi ipade akanṣe kan to waye niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa. Lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keji yii, ni wọn ti wa lẹnu ipade naa, ki wọn too ṣẹṣẹ fẹnu ko laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹta ipade wọn.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i kede ipinnu yii faye gbọ, olobo kan to ṣofofo ohun to n lọ nipade naa sọ fun iweeroyin Leadership pe lẹyin ti wọn yiri ọrọ naa sọtun-un, ti wọn yiri ẹ sosi, wọn fẹnu ko pe ki Aarin-Gungbun Ariwa ilẹ wa mu alaga APC jade.

Ipinlẹ mẹfa ati olu-ilu wa, Abuja, lo wa ni agbegbe Aarin-Gbungbun Ariwa. Awọn ipinlẹ naa ni: Benue, Kogi, Kwara, Nasarawa, Niger ati Plateau.

Bakan naa la gbọ pe iha Guusu ilẹ wa ni wọn yoo ti mu igbakeji alaga ati akọwe apapọ ẹgbẹ naa, ati pe ipade naa ṣi n tẹsiwaju lati pin awọn ipo to ku ninu igbimọ alakooso ẹgbẹ ọhun sawọn agbegbe mi-in.

A tun gbọ pe awọn gomina kan ti n ṣatilẹyin fun gomina ipinlẹ Benue tẹlẹ George Akume, lati bọ sipo alaga naa.

Wọn ni igbesẹ yii ni yoo mu ki eto idibo lati yan awọn adari ẹgbẹ lọ nirọwọ-rọsẹ lakooko apejọ akanṣe ẹgbẹ naa ti yoo waye lopin oṣu keji yii

Pẹlu igbesẹ yii, o ti n foju han pe apa isalẹ  wa nibi ni ẹni ti yoo dije dupo aarẹ yoo ti wa.

Leave a Reply